Job 22:1-30

Job 22:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, Enia le iṣe rere fun Ọlọrun, bi ọlọgbọ́n ti iṣe rere fun ara rẹ̀. Ohun ayọ̀ ha ni fun Olodumare pe, olododo ni iwọ? tabi ere ni fun u, ti iwọ mu ọ̀na rẹ pé? Yio ha ba ọ wi bi nitori ìbẹru Ọlọrun rẹ, yio ha ba ọ lọ sinu idajọ bi? Iwa-buburu rẹ kò ha tobi, ati ẹ̀ṣẹ rẹ lainiye? Nitõtọ iwọ gbà ohun ẹri li ọwọ arakunrin rẹ lainidi, iwọ si tú onihoho li aṣọ wọn. Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa. Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀. Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́. Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu. Tabi iwọ kò ha ri okunkun, ati ọ̀pọlọpọ omi ti o bò ọ mọlẹ? Ọlọrun kò ha jẹ Ẹni giga ọrun? sa wò ori awọn ìrawọ̀ bi nwọn ti ga tó! Iwọ si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀, on ha le iṣe idajọ lati inu awọsanma dudu wá bi? Awọsanma ti o nipọn ni ibora fun u, ti kò fi le riran; o si rin ninu ayika ọrun. Iwọ fẹ rìn ipa-ọ̀na igbani ti awọn enia buburu ti rìn. Ti a ke lulẹ kuro ninu aiye laipé ọjọ wọn, ipilẹ wọn ti de bi odò ṣiṣàn. Awọn ẹniti o wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa! Kini Olodumare yio ṣe fun wọn. Sibẹ o fi ohun rere kún ile wọn! ṣugbọn ìmọ enia-buburu jìna si mi! Awọn olododo ri i, nwọn si yọ̀, awọn alailẹ̀ṣẹ si fi wọn rẹrin ẹlẹya pe: Lotitọ awọn ọta wa ni a ke kuro, iná yio si jó iyokù wọn run. Fa ara rẹ sunmọ Ọlọrun, iwọ o si ri alafia; nipa eyinì rere yio wá ba ọ. Emi bẹ̀ ọ, gba ofin lati ẹnu rẹ̀ wá, ki o si tò ọ̀rọ rẹ̀ si aiya rẹ. Bi iwọ ba yipada sọdọ Olodumare, a si gbe ọ ró, bi iwọ ba si mu ẹ̀ṣẹ jina rére kuro ninu agọ rẹ. Ti iwọ ba tẹ wura daradara silẹ lori erupẹ ati wura ófiri labẹ okuta odò. Nigbana ni Olodumare yio jẹ iṣura rẹ, ani yio si jẹ fadaka fun ọ ni ọ̀pọlọpọ. Lotitọ nigbana ni iwọ o ni inu didùn ninu Olodumare, iwọ o si gbe oju rẹ soke sọdọ Ọlọrun. Bi iwọ ba gbadura rẹ sọdọ rẹ̀, yio si gbọ́ tirẹ, iwọ o si san ẹ̀jẹ́ rẹ. Iwọ si gbimọ ohun kan pẹlu, yio si fi idi mulẹ fun ọ; imọlẹ yio si mọ́ sipa ọ̀na rẹ. Nigbati ipa-ọ̀na rẹ ba lọ sisalẹ, nigbana ni iwọ o wipe, Igbesoke mbẹ! Ọlọrun yio si gba onirẹlẹ là! Yio gba ẹniti kì iṣe alaijẹbi là, a o si gbà a nipa mimọ́ ọwọ rẹ.

Job 22:1-30 Yoruba Bible (YCE)

Elifasi ará Temani bá dáhùn pé, “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun? Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún. Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare, tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé? Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí, tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́? Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin? O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí, O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto. O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu, o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ. Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀, ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀. O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo, o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá. Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká, tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì. Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran, ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀. “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀run Ó ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀ àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ, bí ó ti wù kí wọ́n ga tó! Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’ Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri? Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran, ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run. “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé; ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn? A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó, a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ. Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’ Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn– ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi. Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn, àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun, iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’ “Nisinsinyii gba ti Ọlọrun, kí o sì wà ní alaafia; kí ó lè dára fún ọ. Gba ìtọ́ni rẹ̀, kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn. Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀, tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ, bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀, tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò, bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ, ati fadaka olówó iyebíye rẹ, nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare, o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun. Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́, o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ. Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe, yóo ṣeéṣe fún ọ, ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ. Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀, a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀. A máa gba àwọn aláìṣẹ̀, yóo sì gbà ọ́ là, nípa ìwà mímọ́ rẹ.”

Job 22:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé: “Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run? Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀? Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ? Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé? “Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí? Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye? Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn. Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa. Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀, ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀. Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo; Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́. Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu, Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran; Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀. “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run? Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó! Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀? Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí? Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un, tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run. Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn ènìyàn búburú tí rìn? A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn; ìpìlẹ̀ wọn ti da bí odò ṣíṣàn; Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa! Kí ni Olódùmarè yóò ṣe fún wọn?’ Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn! Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi! Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀, àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé, ‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò, iná yóò sì jó oró wọn run.’ “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà; nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ. Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá, kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ. Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró: Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ, Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀ lórí erùpẹ̀ àti wúrà ofiri lábẹ́ òkúta odò, Nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ, ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ. Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ; ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ. Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀, nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’ Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là! Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là, a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”