Job 21:17-34

Job 21:17-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

Igba melomelo ni a npa fitila enia buburu kú? igba melomelo ni iparun wọn de ba wọn, ti Ọlọrun isi ma pin ibinujẹ ninu ibinu rẹ̀. Nwọn dabi akeku oko niwaju afẹfẹ, ati bi iyangbo, ti ẹfufu-nla fẹ lọ. Ọlọrun to ìya-ẹ̀ṣẹ rẹ̀ jọ fun awọn ọmọ rẹ̀, o san a fun u, yio si mọ̀ ọ. Oju rẹ̀ yio ri iparun ara rẹ̀, yio si ma mu ninu riru ibinu Olodumare. Nitoripe alafia kili o ni ninu ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati a ba ke iye oṣù rẹ̀ kuro li agbedemeji? Ẹnikẹni le ikọ́ Ọlọrun ni ìmọ? on ni sa nṣe idajọ ẹni ibi giga. Ẹnikan a kú ninu pipé agbara rẹ̀, ti o wà ninu irọra ati idakẹ patapata. Ọpọ́n rẹ̀ kún fun omi-ọmú, egungun rẹ̀ si tutu fun ọra. Ẹlomiran a si kú ninu kikoro ọkàn rẹ̀, ti kò si fi inu didun jẹun. Nwọn o dubulẹ bakanna ninu erupẹ, kòkoro yio si ṣùbo wọn. Kiyesi i, emi mọ̀ iro inu nyin ati arekereke ti ẹnyin fi gba dulumọ si mi. Nitoriti ẹnyin wipe, nibo ni ile awọn ọmọ alade, ati nibo ni agọ awọn enia buburu nì gbe wà? Ẹnyin kò bere lọwọ awọn ti nkọja lọ li ọ̀na, ẹnyin kò mọ̀ àmi wọn? pe, Enia buburu ni a fi pamọ fun ọjọ iparun, a o si mu wọn jade li ọjọ riru ibinu. Tani yio sọ ipa-ọ̀na rẹ̀ kò o li oju, tani yio si san pada fun u li eyi ti o ti ṣe? Sibẹ a o si sin i li ọ̀na ipo-okú, yio si ma ṣọ́ ororì okú. Ogulutu ọfin yio dùn mọ ọ, gbogbo enia yio si ma tọ̀ ọ lẹhin, bi enia ainiye ti lọ ṣiwaju rẹ̀. E ha ti ṣe ti ẹnyin fi ntù mi ninu lasan! bi o ṣepe ni idahùn nyin eké kù nibẹ.

Job 21:17-34 Yoruba Bible (YCE)

“Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi? Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí? Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀? Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri, tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ? “O ní, ‘Ọlọrun ń to àìdára wọn jọ de àwọn ọmọ wọn.’ Jẹ́ kí ó dà á lé wọn lórí, kí wọ́n baà lè mọ ohun tí wọ́n ṣe. Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn, kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare. Kí ni ó kàn wọ́n pẹlu ilé wọn mọ́, lẹ́yìn tí wọn bá ti kú, nígbà tí a bá ti ké ọjọ́ wọn kúrò lórí ilẹ̀. Ṣé ẹnìkan lè kọ́ Ọlọrun ní ìmọ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni onídàájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ibi gíga? Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀, nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà, ara rẹ̀ ń dán fún sísanra, ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn. Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn, láìtọ́ ohun rere kankan wò rí. Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀, tí ìdin sì bò wọ́n. “Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín, mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi. Nítorí ẹ wí pé, ‘Níbo ni ilé àwọn eniyan ńlá wà; níbo sì ni àgọ́ àwọn aṣebi wà?’ Ṣé ẹ kò tíì bèèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn arìnrìnàjò? Ṣé ẹ kò sì tíì gba ẹ̀rí wọn, pé, a dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, ati pé a gbà á là ní ọjọ́ ibinu? Kò sẹ́ni tó jẹ́ fẹ̀sùn kan ẹni ibi lójú rẹ̀, tabi kí ó gbẹ̀san nǹkan burúkú tí ó ṣe. Nígbà tí a bá gbé e lọ sí itẹ́, àwọn olùṣọ́ a máa ṣọ́ ibojì rẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹrun èrò a tẹ̀lé e lọ sí ibojì, àìmọye eniyan a sì sin òkú rẹ̀; kódà, ilẹ̀ á dẹ̀ fún un ní ibojì rẹ̀. Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu? Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín, tó ju irọ́ lọ.”

Job 21:17-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀? Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ. Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n. Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè. Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì? “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀? Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga. Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá. Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá. Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun. Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n. “Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi. Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé, àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’ Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà? Ẹ̀yin kò mọ̀ ààmì wọn, pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun. A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú. Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe? Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú. Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn. Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀. “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán, bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”