Job 20:1-29
Job 20:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe, Nitorina ni ìro inu mi da mi lohùn, ati nitori eyi na ni mo si yara si gidigidi. Mo ti gbọ́ ẹsan ẹ̀gan mi, ẹmi oye mi si da mi lohùn. Iwọ kò mọ̀ eyi ri ni igba atijọ, lati igba ti a sọ enia lọjọ̀ silẹ aiye? Pe, orin ayọ̀ enia buburu igba kukuru ni, ati pe, ni iṣẹju kan li ayọ̀ àgabagebe. Bi ọlanla rẹ̀ tilẹ goke de ọrun, ti ori rẹ̀ si kan awọsanma. Ṣugbọn yio ṣegbe lailai bi igbẹ́ ara rẹ̀; awọn ti o ti ri i rí, yio wipe, On ha dà? Yio fò lọ bi alá, a kì yio si ri i, ani a o lé e lọ bi iran oru. Oju ti o ti ri i rí pẹlu, kì yio si ri i mọ́, bẹ̃ni ibujoko rẹ̀ kì yio si ri i mọ́. Awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wá ati ri oju-rere lọdọ talaka, ọwọ rẹ̀ yio si kó ẹrù wọn pada. Egungun rẹ̀ kún fun agbara igba ewe rẹ̀, ti yio ba a dubulẹ ninu erupẹ. Bi ìwa buburu tilẹ dùn li ẹnu rẹ̀, bi o tilẹ pa a mọ́ nisalẹ ahọn rẹ̀. Bi o tilẹ dá a si, ti kò si kọ̀ ọ silẹ, ti o pa a mọ sibẹ li ẹnu rẹ̀, Ṣugbọn onjẹ rẹ̀ ninu ikùn rẹ̀ ti yipada, o jasi orõro pamọlẹ ninu rẹ̀; O ti gbe ọrọ̀ mì, yio si tun bì i jade, Ọlọrun yio pọ̀ ọ yọ jade lati inu rẹ̀ wá. O ti fà oró pamọlẹ mu, ahọn gunte ni yio pa a. Kì yio ri odò wọnni, iṣan omi, odò ṣiṣàn oyin ati ti ori amọ́. Ohun ti o ṣíṣẹ fun ni yio mu u pada, kì yio si gbe e mì; gẹgẹ bi ọrọ̀ ti o ni, kì yio si yọ̀ ninu rẹ̀. Nitoriti o ninilara, o si ti kẹhinda talaka, nitoriti o fi agbara gbe ile ti on kò kọ́. Nitori on kò mọ̀ iwa-pẹlẹ ninu ara rẹ̀, ki yio si gbà ninu eyiti ọkàn rẹ̀ fẹ silẹ. Ohun kan kò kù fun jijẹ rẹ̀, nitorina ọrọ̀ rẹ̀ kì yio duro pẹ́. Ninu titó ìkún rẹ̀ yio wà ninu ihale, ọwọ gbogbo awọn oniyọnu ni yio dide si i lori. Yio si ṣe pe, nigbati o ma fi kún inu rẹ̀ yo nì, Ọlọrun yio fa riru ibinu rẹ̀ si i lori, nigbati o ba njẹun lọwọ. Yio sá kuro lọwọ ohun-ogun irin, ọrun akọ-irin ni yio ta a po yọ. O fà a yọ, o si jade kuro lara, ani idà didan ni njade lati inu orõro wá: ẹ̀ru-nla mbẹ li ara rẹ̀. Okunkun gbogbo ni a ti pamọ́ fun iṣura rẹ̀, iná ti a kò fẹ́ ni yio jo o run: yio si jẹ eyi ti o kù ninu agọ rẹ̀ run. Ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ rẹ̀ hàn, aiye yio si dide duro si i. Ibisi ile rẹ̀ yio kọja lọ, ati ohun ini rẹ̀ yio ṣàn danu lọ li ọjọ ibinu Ọlọrun. Eyi ni ipin enia buburu lati ọdọ Ọlọrun wá, ati ogún ti a yàn silẹ fun u lati ọdọ Oluwa wá.
Job 20:1-29 Yoruba Bible (YCE)
Sofari, ará Naama bá dáhùn pé, “Lọ́kàn mi, mo fẹ́ fèsì sí ọ̀rọ̀ rẹ, ara sì ń wá mi, bí ẹni pé kí n dá ọ lóhùn. Mo gbọ́ èébú tí o bú mi, mo sì mọ irú èsì tí ó yẹ kí n fọ̀. Ṣé o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí wọ́n ti dá eniyan sórí ilẹ̀ ayé, pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn, tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni. Bí ìgbéraga rẹ̀ tilẹ̀ ga, tí ó kan ọ̀run, tí orí rẹ̀ kan sánmà, yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀, àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’ Yóo parẹ́ bí àlá, yóo sì di àwátì, yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru. Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́, ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní, wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada. Bí ó tilẹ̀ dàbí ọ̀dọ́, tí ó lágbára, sibẹ yóo lọ sí ibojì, yóo sì di erùpẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ ìkà tilẹ̀ dùn ní ẹnu rẹ̀, tí ó sì fi pamọ́ sí abẹ́ ahọ́n rẹ̀, bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde, tí ó pa ẹnu mọ́, sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú, ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀. Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde; Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀. Yóo mu oró ejò, ahọ́n paramọ́lẹ̀ yóo pa á. Kò ní gbádùn oyin ati wàrà tí ń ṣàn bí odò. Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀. Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀, ó sì ti pa wọ́n tì sí apákan ó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́. Nítorí pé oníwọ̀ra ni, tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan, kò lè pa á mọ́ra. Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù, nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́. Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́, ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà. Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó, ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i, tí yóo sì dà lé e lórí. Bí ó bá ti ń sá fún idà, bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji. Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀, tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀, ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a. Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é, iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun, ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun. Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn, ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́. Ibinu Ọlọrun gba àwọn ohun ìní rẹ̀ lọ, àgbàrá ibinu yóo gbá wọn dànù. Bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ibi yóo rí. Ọlọrun ni ó ti yàn án bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ wá.”
Job 20:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé: “Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn, àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi. Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn. “Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé, pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè? Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀; Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’ Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru. Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà. Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀. “Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀, bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀, Ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà, ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀; Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá. Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú; ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á. Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́. Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀. Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n; Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́. “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀. Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀; Nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́. Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a; àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí. Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun, Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí. Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ. O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá. Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀; òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀. Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run. Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóò sì dìde dúró sí i. Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run. Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”