Job 2:7-9
Job 2:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa, o si sọ Jobu li õwo kikankikan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ de atari rẹ̀. O si mu apadì o fi nhá ara rẹ̀, o si joko ninu ẽru. Nigbana ni aya rẹ̀ wi fun u pe, iwọ di ìwa otitọ rẹ mu sibẹ! bu Ọlọrun, ki o si kú.
Pín
Kà Job 2Job 2:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Satani bá lọ kúrò níwájú OLUWA, ó sì da oówo bo Jobu lára, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé orí. Jobu ń fi àpáàdì họ ara, ó sì jókòó sinu eérú. Iyawo Jobu bá sọ fún un pé, “Orí òtítọ́ inú rẹ ni o tún wà sibẹ? Fi Ọlọrun bú, kí o kú.”
Pín
Kà Job 2Job 2:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú OLúWA, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú. Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!”
Pín
Kà Job 2