Job 19:1-29
Job 19:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o fi ma bà mi ninu jẹ, ti ẹnyin o fi ma fi ọ̀rọ kun mi ni ìjanja? Igba mẹwa li ẹnyin ti ngàn mi, oju kò tì nyin ti ẹ fi jẹ mi niya. Ki a fi sí bẹ̃ pe, mo ṣìna nitõtọ, ìṣina mi wà lara emi tikarami. Bi o tilẹ ṣepe ẹnyin o ṣogo si mi lori nitõtọ, ti ẹ o si ma fi ẹ̀gan mi gun mi loju. Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka. Kiyesi i, emi nkigbe pe, Ọwọ́ alagbara! ṣugbọn a kò gbọ́ ti emi; mo kigbe soke, bẹ̃ni kò si idajọ. O sọ̀gba di ọ̀na mi ti emi kò le kọja, o si mu òkunkun ṣú si ipa ọ̀na mi: O ti bọ́ ogo mi, o si ṣi ade kuro li ori mi. O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi: O si tinabọ ibinu rẹ̀ si mi, o si kà mi si bi ọkan ninu awọn ọta rẹ̀. Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ si dàpọ si mi, nwọn si tẹgun si mi, nwọn si dó yi agọ mi ka. O mu awọn arakunrin mi jina si mi rére, ati awọn ojulumọ mi di ajeji si mi nitõtọ. Awọn ajọbi mi fà sẹhin, awọn afaramọ́ ọrẹ mi si di onigbagbe mi. Awọn ara inu ile mi ati awọn ọmọbinrin iranṣẹ mi kà mi si ajeji, emi jasi ajeji enia li oju wọn. Mo pè iranṣẹ mi, on kò si da mi lohùn, mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ. Ẹmi mi sú aya mi, ati õrùn mi sú awọn ọmọ inu iya mi. Ani awọn ọmọde fi mi ṣẹsin: mo dide, nwọn si sọ̀rọ ẹ̀gan si mi. Gbogbo awọn ọrẹ idimọpọ mi korira mi, awọn olufẹ mi si kẹ̀hinda mi. Egungun mi lẹ mọ́ awọ ara mi ati mọ́ ẹran ara mi, mo si bọ́ pẹlu awọ ehin mi. Ẹ ṣãnu fun mi, ẹ ṣãnu fun mi, ẹnyin ọrẹ mi, nitori ọwọ Ọlọrun ti bà mi. Nitori kili ẹnyin ṣe lepa mi bi Ọlọrun, ti ẹran ara mi kò tẹ́ nyin lọrùn! A! Ibaṣepe a le kọwe ọ̀rọ mi nisisiyi, ibaṣepe a le dà a sinu iwe! Ki a fi kalamu irin ati ti ojé kọ́ wọn sinu apata fun lailai. Ati emi, emi mọ̀ pe Oludande mi mbẹ li ãyè, ati pe on bi Ẹni-ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ. Ati lẹhin igba awọ ara mi, ti a ti ke e kuro bi iru eyi, ati laili ẹran ara mi li emi o ri Ọlọrun, Ẹniti emi o ri fun ara mi, ti oju mi o si wò, kì si iṣe ti ẹlomiran; ọkàn mi si dáku ni inu mi. Bi ẹnyin ba wipe, Awa o ti lepa rẹ̀ to! ati pe, gbongbo ọ̀rọ na li a sa ri li ọwọ mi, Ki ẹnyin ki o bẹ̀ru idà; nitoripe ibinu ni imu ijiya idà wá: ki ẹnyin ki o lè imọ̀ pe idajọ kan mbẹ.
Job 19:1-29 Yoruba Bible (YCE)
Jobu bá dáhùn, ó ní, “Ẹ óo ti ni mí lára pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ọ̀rọ̀ yín bà mí ninu jẹ́? Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbà ojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí? Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀, ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà? Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ, tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi, ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi, tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká. Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn; mo pariwo, pariwo, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́. Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá, ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn. Ó bọ́ ògo mi kúrò, ó sì gba adé orí mi. Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà, ó sì ti parí fún mi, ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu. Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná, ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n dó tì mí, wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká. “Ó mú kí àwọn arakunrin mi jìnnà sí mi, àwọn ojúlùmọ̀ mi sì di àjèjì sí mi. Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀. Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi. Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò, wọ́n ń wò mí bí àjèjì. Mo pe iranṣẹ mi, ṣugbọn kò dáhùn, bíbẹ̀ ni mo níláti máa bẹ̀ ẹ́. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ iyawo mi, mo sì ń rùn sí àwọn ọmọ ìyá mi. Àwọn ọmọde pàápàá ń fojú tẹmbẹlu mi; bí mo bá dìde wọn á máa sọ̀rọ̀ sí mi. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti rí mi sá, àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi. Mo rù kan egungun, agbára káká ni mo fi sá àsálà. Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí! Ọlọrun ń lépa mi, ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi! Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín? “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀! Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé! Kí á fi kálàmú irin ati òjé kọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae. Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè, ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi, lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́, ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run. Fúnra mi ni n óo rí i, ojú ara mi ni n óo sì fi rí i, kì í ṣe ti ẹlòmíràn. “Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi! Bí ẹ bá wí pé, ‘Báwo ni a óo ṣe lépa rẹ̀!’ Nítorí pé òun ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, ṣugbọn, ẹ bẹ̀rù idà, nítorí pé ìrúnú níí fa kí á fi idà pa eniyan, kí ẹ lè mọ̀ dájú pé ìdájọ́ ń bẹ.”
Job 19:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí? Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí; ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà. Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́, ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú, Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká. “Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi; mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́. Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi. Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi. Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi. Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká. “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá. Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi. Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì; èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn. Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn; mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́. Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi. Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín: Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí. Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi, mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi. “Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí. Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn? “Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsin yìí, ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé! Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ wọ́n sínú àpáta fún láéláé. Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn; Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run, Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn; ọkàn mi sì dákú ní inú mi. “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó! Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’ Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù; nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà, Kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”