Job 17:1-16
Job 17:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI mi bajẹ, ọjọ mi parun, isa-okú duro dè mi. Nitõtọ! awọn ẹlẹya wà lọdọ mi, oju mi si tẹmọ́ imunibinu wọn. Njẹ nisisiyi, fi lelẹ! yàn onigbọwọ fun mi lọdọ rẹ; tani oluwa rẹ̀ ti yio ba mi so ọwọ pọ̀? Nitoripe iwọ ti sé wọn laiya kuro ninu oye, nitorina iwọ kì yio gbé wọn leke. Ẹniti o fi awọn ọrẹ hàn fun igára, on ni oju awọn ọmọ rẹ̀ yio mu ofo. O si sọ mi di ẹni-owe fun awọn enia, niwaju wọn ni mo dabi ẹni itutọ́ si li oju. Oju mi ṣú baibai pẹlu nitori ibinujẹ, gbogbo ẹ̀ya ara mi si dabi ojiji. Awọn olododo yio yanu si eyi, ẹni alaiṣẹ̀ si binu si awọn àgabagebe. Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju. Ṣugbọn bi o ṣe ti gbogbo nyin, ẹ yipada, ki ẹ si tun bọ̀ nisisiyi, emi kò le ri ọlọgbón kan ninu nyin. Ọjọ ti emi ti kọja, iro mi ti fà já, ani iro inu mi. A sọ oru di ọ̀san; nwọn ni, imọlẹ sunmọ ibiti òkunkun de. Bi mo tilẹ ni ireti, ipo-okú ni ile mi, mo ti tẹ bùsun mi sinu òkunkun. Emi ti wi fun idibajẹ pe, Iwọ ni baba mi, ati fun kòkoro pe, Iwọ ni iya mi ati arabinrin mi. Ireti mi ha dà nisisiyi? bi o ṣe ti ireti mi ni, tani yio ri i? O sọkalẹ lọ sinu ọgbun ipo-okú, nigbati a jumọ simi pọ̀ ninu erupẹ ilẹ.
Job 17:1-16 Yoruba Bible (YCE)
“Ọkàn mi bàjẹ́, ọjọ́ ayé mi ti dópin, ibojì sì ń dúró dè mí. Dájúdájú àwọn ẹlẹ́yà yí mi káàkiri, wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ lojukooju. Fi nǹkan ẹ̀jẹ́ kan lélẹ̀ fún mi lọ́dọ̀ rẹ; ta ló wà níbẹ̀ tí yóo ṣe onídùúró fún mi? Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀, nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí. Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́, kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn, àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà. O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan, mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì, gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji. Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu, aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun. Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i. Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín. “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú, àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán. Wọ́n sọ òru di ọ̀sán, wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’ Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi, tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn, bí mo bá pe isà òkú ní baba, tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi, níbo ni ìrètí mi wá wà? Ta ló lè rí ìrètí mi? Ṣé yóo lọ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni? Ṣé àwa mejeeji ni yóo jọ wọ inú erùpẹ̀ lọ?”
Job 17:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ̀mí mi bàjẹ́, ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú, isà òkú dúró dè mí. Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi, ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn. “Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́; ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi? Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè. Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo. “Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú. Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji. Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí, ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè. Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú. “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí; èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín. Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá, àní ìrò ọkàn mi. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé. Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi; mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn. Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi, àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi, ìrètí mi ha dà nísinsin yìí? Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i? Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú, nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”