Job 16:2-4
Job 16:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ti gbọ́ iru ohun pipọ bẹ̃ ri; ayọnilẹnu onitunu enia ni gbogbo nyin. Ọ̀rọ asan lè ni opin? tabi kili o gbó ọ laiya ti iwọ fi dahùn. Emi pẹlu le isọ bi ẹnyin, bi ọkàn nyin ba wà ni ipò ọkàn mi, emi le iko ọ̀rọ pọ̀ si nyin li ọrùn, emi a si mì ori mi si nyin.
Job 16:2-4 Yoruba Bible (YCE)
“Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí, ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin? Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí? Bí ẹ bá wà ní ipò mi, èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí, kí n da ọ̀rọ̀ bò yín, kí n sì máa mi orí si yín.
Job 16:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín. Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn? Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn, èmi a sì mi orí mi sí i yín.