Job 16:1-22
Job 16:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe, Emi ti gbọ́ iru ohun pipọ bẹ̃ ri; ayọnilẹnu onitunu enia ni gbogbo nyin. Ọ̀rọ asan lè ni opin? tabi kili o gbó ọ laiya ti iwọ fi dahùn. Emi pẹlu le isọ bi ẹnyin, bi ọkàn nyin ba wà ni ipò ọkàn mi, emi le iko ọ̀rọ pọ̀ si nyin li ọrùn, emi a si mì ori mi si nyin. Emi iba fi ọ̀rọ ẹnu mi gbà nyin ni iyanju, ati ṣiṣi ète mi iba si tu ibinujẹ nyin. Bi emi tilẹ sọ̀rọ ibinujẹ mi kò rù; bi mo si tilẹ dakẹ, nibo li itunu mi de? Ṣugbọn nisisiyi, o da mi lagara, iwọ (Ọlọrun) mu gbogbo ẹgbẹ mi takete. Iwọ si fi ikiweje kún mi lara, ti o jẹri tì mi; ati rirù ti o yọ lara mi, o jẹri tì mi li oju. Ibinu rẹ̀ li o fà mi ya, o si ṣọta mi; o pa ehin rẹ̀ keke si mi, ọta mi si gboju rẹ̀ si mi. Nwọn ti fi ẹnu wọn yán si mi, nwọn gbá mi li ẹrẹkẹ ni igbá ẹ̀gan, nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si mi. Ọlọrun ti fi mi le ọwọ ẹni-buburu, o si mu mi ṣubu si ọwọ enia ẹlẹṣẹ. Mo ti joko jẹ, ṣugbọn o fa mi já o si dì mi li ọrùn mu, o si gbọ̀n mi tutu, o si gbe mi kalẹ ṣe àmi itasi rẹ̀. Awọn tafatafa rẹ̀ duro yi mi kakiri; o là mi laiya pẹ̀rẹ kò si dasi, o si tú orõrò ara mi dà silẹ. Ibajẹ lori ibajẹ li o fi ba mi jẹ; o sure kọlù mi bi òmirán. Mo rán aṣọ-apo bò ara mi, mo si rẹ̀ iwo mi silẹ ninu erupẹ. Oju mi ti pọ́n fun ẹkún, ojiji ikú si ṣẹ si ipenpeju mi. Kì iṣe nitori aiṣotitọ kan li ọwọ mi, adura mi si mọ́ pẹlu. A! ilẹ aiye, iwọ máṣe bò ẹ̀jẹ mi, ki ẹkún mi máṣe ni ipò kan. Njẹ nisisiyi kiyesi i! ẹlẹri mi mbẹ li ọrun, ẹri mi si mbẹ loke ọrun. Awọn ọre mi nfi mi ṣẹ̀sin, ṣugbọn oju mi ndà omije sọdọ Ọlọrun. Ibaṣepe ẹnikan le ma ṣe alagbawi fun ẹnikeji lọdọ Ọlọrun, bi enia kan ti iṣe alagbawi fun ẹnikeji rẹ̀. Nitori nigbati iye ọdun diẹ rekọja tan, nigbana ni emi o lọ si ibi ti emi kì yio pada bọ̀.
Job 16:1-22 Yoruba Bible (YCE)
Jobu bá dáhùn pé, “Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí, ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin? Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí? Bí ẹ bá wà ní ipò mi, èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí, kí n da ọ̀rọ̀ bò yín, kí n sì máa mi orí si yín. Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun, kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín. “Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí, bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi? Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara, ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro. Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí; rírù tí mo rù ta àbùkù mi, ó sì hàn lójú mi. Ó ti fi ibinu fà mí ya, ó sì kórìíra mi; ó pa eyín keke sí mi; ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí. Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń gbá mi létí, wọ́n kó ara wọn jọ sí mi. Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́, ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà. Nígbà tí ó dára fún mi, ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀, ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀, ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́; ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí. Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká, ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi, ó sì tú òróòro mi jáde. Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo, ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun. “Mo fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, mo sùn gbalaja sinu erùpẹ̀. Mo sọkún títí ojú mi fi pọ́n, omijé sì mú kí ojú mi ṣókùnkùn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ibi, adura mi sì mọ́. “Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀, má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo. Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run, alágbàwí mi sì ń bẹ lókè. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, mo sì ń sọkún sí Ọlọrun, ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun, bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i, n óo lọ àjò àrèmabọ̀.
Job 16:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín. Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn? Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn, èmi a sì mi orí mi sí i yín. Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín. “Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ; bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò? Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara; Ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété. Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú. Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí; ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi. Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi; Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn; Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi. Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà. Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe ààmì ìtafàsí rẹ̀; àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri. Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀. Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́; ó súré kọlù mi bí jagunjagun. “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi, mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀. Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi. Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́ mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú. “Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi, kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan. Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run; Ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀. “Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.