Job 16:1-14

Job 16:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Jobu bá dáhùn pé, “Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí, ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin? Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí? Bí ẹ bá wà ní ipò mi, èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí, kí n da ọ̀rọ̀ bò yín, kí n sì máa mi orí si yín. Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun, kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín. “Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí, bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi? Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara, ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro. Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí; rírù tí mo rù ta àbùkù mi, ó sì hàn lójú mi. Ó ti fi ibinu fà mí ya, ó sì kórìíra mi; ó pa eyín keke sí mi; ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí. Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń gbá mi létí, wọ́n kó ara wọn jọ sí mi. Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́, ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà. Nígbà tí ó dára fún mi, ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀, ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀, ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́; ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí. Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká, ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi, ó sì tú òróòro mi jáde. Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo, ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun.

Job 16:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín. Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn? Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn, èmi a sì mi orí mi sí i yín. Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín. “Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ; bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò? Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara; Ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété. Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú. Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí; ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi. Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi; Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn; Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi. Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà. Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe ààmì ìtafàsí rẹ̀; àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri. Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀. Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́; ó súré kọlù mi bí jagunjagun.