Job 15:1-13
Job 15:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, Ọlọgbọ́n a ma sọ̀rọ ìmọ asan, ki o si ma fi afẹfẹ ila õrùn kún ara rẹ̀ ninu: On le ma fi aroye sọ̀rọ ti kò li ère, tabi pẹlu ọ̀rọ ninu eyiti kò le fi ṣe rere? Ani iwọ ṣa ìbẹru tì, iwọ si dí adura lọna niwaju Ọlọrun. Nitoripe ẹnu ara rẹ li o jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ, iwọ si yàn ahọn alarekereke li ãyò. Ẹnu ara rẹ li o da ọ lẹbi, kì iṣe emi, ani ète ara rẹ li o jẹri tì ọ. Iwọ́ ha iṣe ọkunrin ti a kọ́ bi? tabi a ha dá ọ ṣaju awọn oke? Iwọ gburo aṣiri Ọlọrun ri, tabi iwọ ha dá ọgbọ́n duro sọdọ ara rẹ? Kini iwọ mọ̀ ti awa kò mọ̀, oye kili o ye ọ ti kò si ninu wa. Elewú ogbó ati ògbologbo enia wà pẹlu wa, ti nwọn gbó jù baba rẹ lọ. Itunu Ọlọrun ha kere lọdọ rẹ, ọ̀rọ kan si ṣe jẹjẹ jù lọdọ rẹ. Ẽṣe ti aiya rẹ fi ndà ọ kiri, tabi kini iwọ tẹjumọ wofin. Ti iwọ fi yi ẹmi rẹ pada lodi si Ọlọrun, ti o fi njẹ ki ọ̀rọkọrọ ki o ma bọ li ẹnu rẹ bẹ̃?
Job 15:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Elifasi ará Temani bá dáhùn pé, “Ṣé ọlọ́gbọ́n a máa fọ èsì tí kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́? Kí ó dàbí àgbá òfìfo? Kí ó máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tabi ọ̀rọ̀ tí kò níláárí? Ṣugbọn ò ń kọ ìbẹ̀rù Ọlọrun sílẹ̀, o sì ń dènà adura níwájú rẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni ó ń fa irú ọ̀rọ̀ tí ń ti ẹnu rẹ jáde, ètè rẹ sì kún fún àrékérekè. Ẹnu rẹ ni ó dá ọ lẹ́bi, kì í ṣe èmi; ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa rẹ ní ń ta kò ọ́. “Ṣé ìwọ ni ẹni kinni tí wọ́n kọ́ bí láyé? Tabi o ṣàgbà àwọn òkè? Ṣé o wà ninu ìgbìmọ̀ Ọlọrun? Tabi ìwọ nìkan ni o rò pé o gbọ́n? Kí ni o mọ̀, tí àwa náà kò mọ̀? Òye kí ni o ní, tí ó jẹ́ ohun ìpamọ́ fún àwa? Àwọn tí wọ́n hu ewú lórí wà láàrin wa, ati àwọn àgbàlagbà, àwọn tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ. Ṣé ìtùnú Ọlọrun kò tó fún ọ ni, àní ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń sọ fún ọ? Àgbéré kí lò ń ṣe, tí o sì ń fi ojú burúkú wò wá. Tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí ò ń jẹ́ kí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ti ẹnu rẹ jáde?
Job 15:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé: “Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú? Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere? Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run. Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò. Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi; àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́. “Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí? Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè? Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí, tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ? Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀? Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa? Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ. Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ? Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ? Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri, kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀. Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?