Job 14:7-12
Job 14:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe abá wà fun igi, bi a ba ke e lulẹ, pe yio si tun sọ, ati pe ẹka rẹ̀ titun, kì yio dá. Bi gbongbo rẹ̀ tilẹ di ogbó ninu ilẹ, ti kukute rẹ̀ si kú ni ilẹ. Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko. Ṣugbọn enia kú, a si ṣàn danu; ani enia jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, on ha da? Bi omi ti itán ninu ipa odò, ti odò si ifà ti si igbẹ. Bẹ̃li enia dubulẹ ti kò si dide mọ́, titi ọrun kì yio fi si mọ́, nwọn kì yio ji, a kì yio ji wọn kuro loju orun wọn.
Job 14:7-12 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé, yóo tún pada rúwé, ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ sì kú, bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ, yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn. Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì, bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí. Bí adágún omi tíí gbẹ, ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn, tí kì í sìí jí mọ́, títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí, tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun.
Job 14:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀; Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn. Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù; Àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́. “Bí omi ti í tán nínú ipa odò, àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́; títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.