Job 14:1-9
Job 14:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
ENIA ti a bi ninu obinrin ọlọjọ diẹ ni, o si kún fun ipọnju. O jade wá bi itana eweko, a si ke e lulẹ, o si nfò lọ bi ojiji, kò si duro pẹ́. Iwọ si nṣiju rẹ wò iru eyinì, iwọ si mu mi wá sinu idajọ pẹlu rẹ. Tali o le mu ohun mimọ́ lati inu aimọ́ jade wá? kò si ẹnikan! Njẹ ati pinnu ọjọ rẹ̀, iye oṣu rẹ̀ mbẹ li ọwọ rẹ, iwọ ti pàla rẹ̀, bẹ̃li on kò le ikọja rẹ̀. Yipada kuro lọdọ rẹ̀, ki o le simi titi yio fi pé ọjọ rẹ̀ bi alagbaṣe. Nitoripe abá wà fun igi, bi a ba ke e lulẹ, pe yio si tun sọ, ati pe ẹka rẹ̀ titun, kì yio dá. Bi gbongbo rẹ̀ tilẹ di ogbó ninu ilẹ, ti kukute rẹ̀ si kú ni ilẹ. Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko.
Job 14:1-9 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹnikẹ́ni tí obinrin bá bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ìpọ́njú. Yóo kọ́ yọ bí òdòdó, lẹ́yìn náà yóo sì rẹ̀ dànù. Yóo kọjá lọ bí òjìji, kò sì ní sí mọ́. Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni o dojú kọ, tí ò ń bá ṣe ẹjọ́? Ta ló lè mú ohun mímọ́ jáde láti inú ohun tí kò mọ́? Kò sí ẹni náà. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un, tí o mọ iye oṣù rẹ̀, tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá. Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi, kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe. “Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé, yóo tún pada rúwé, ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ sì kú, bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ, yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn.
Job 14:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin, ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú. Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀; ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́. Ìwọ sì ń ṣíjú rẹ wò irú èyí ni? Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ? Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan! Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; Ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀. Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe. “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀; Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.