Job 13:1-19
Job 13:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wò o, oju mi ti ri gbogbo eyi ri, eti mi si gbọ́ o si ti ye e. Ohun ti ẹnyin mọ̀, emi mọ̀ pẹlu, emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin. Nitotọ emi o ba Olodumare sọ̀rọ, emi si nfẹ ba Ọlọrun sọ asọye. Ẹnyin ni onihumọ eke, oniṣegun lasan ni gbogbo nyin. O ṣe! ẹ ba kuku pa ẹnu nyin mọ patapata! eyini ni iba si ṣe ọgbọ́n nyin. Ẹ gbọ́ awiye mi nisisiyi, ẹ si fetisilẹ si aroye ẹnu mi. Ẹnyin fẹ sọ isọkusọ fun Ọlọrun? ki ẹ si fi ẹ̀tan sọ̀rọ gbè e? Ẹnyin fẹ ṣojusaju rẹ̀, ẹnyin fẹ igbìjà fun Ọlọrun? O ha dara ti yio fi hudi nyin silẹ, tabi ki ẹnyin tàn a bi ẹnikan ti itan ẹnikeji. Yio ma ba nyin wi nitotọ, bi ẹnyin ba ṣojusaju enia nikọ̀kọ. Iwa ọlá rẹ̀ ki yio bà nyin lẹ̃ru bi? ipaiya rẹ̀ ki yio pá nyin laiya? Iranti nyin dabi ẽru, ilu-odi nyin dabi ilu-odi amọ̀. Ẹ pa ẹnu nyin mọ kuro lara mi, ki emi ki o le sọ̀rọ, ohun ti mbọ̀ wá iba mi, ki o ma bọ̀. Njẹ nitori kili emi ṣe nfi ehin mi bù ẹran ara mi jẹ, ti mo si gbe ẹmi mi le ara mi lọwọ? Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o ma gbẹkẹle e, ṣugbọn emi o ma tẹnumọ ọ̀na mi niwaju rẹ̀. Eyi ni yio si ṣe igbala mi pe: àgabagebe kì yio wá siwaju rẹ̀. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi ni ifaiyabalẹ, ati asọpe mi li eti nyin. Wò o nisisiyi emi ti ladi ọ̀ran mi silẹ; emi mọ̀ pe a ó da mi lare. Tani on ti yio ba mi ṣàroye? njẹ nisisiyi, emi fẹ pa ẹnu mi mọ, emi o si jọwọ ẹmi mi lọwọ.
Job 13:1-19 Yoruba Bible (YCE)
“Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí, tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi. Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n, ẹ kò sàn jù mí lọ. Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́. Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi, ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn. Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni, à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n! Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi, kí ẹ sì fetísí àròyé mi. Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni, kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀? Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni? Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀? Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò? Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan? Dájúdájú, yóo ba yín wí, bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀. Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín, jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín. Àwọn òwe yín kò wúlò, àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi, kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi. N óo dijú, n óo fi ẹ̀mí ara mi wéwu. Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí; sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀. Èyí ni yóo jẹ́ ìgbàlà mi, nítorí pé ẹni tí kò mọ Ọlọrun, kò ní lè dúró níwájú rẹ̀. Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi, kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé. Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀; mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre. Ta ni yóo wá bá mi rojọ́? Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú.
Job 13:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Wò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí, etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé mi. Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú, èmi kò kéré sí i yin. Nítòótọ́ èmi ó bá Olódùmarè sọ̀rọ̀, èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé. Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀, oníṣègùn lásán ni gbogbo yín. Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín. Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsin yìí; ẹ sì fetísílẹ̀ sí àròyé ẹnu mi. Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run? Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é? Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀? Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run? Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta, Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì? Yóò máa bá yín wí nítòótọ́, bí ẹ̀yin bá ṣe ojúsàájú ènìyàn níkọ̀kọ̀. Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí? Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà? Àwọn òwe yín dàbí eérú; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn odi ìlú yin dàbí amọ̀. “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ki ohun tí ń bọ̀ wá í bá mi, le è máa bọ̀. Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi eyín mi bu ẹran-ara mi jẹ, Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́? Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e; Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀. Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi, Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfarabalẹ̀, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí dún ni etí yín. Wò ó nísinsin yìí, èmi ti mura ọ̀ràn mi sílẹ̀; èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre. Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé? Ǹjẹ́ nísinsin yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mi mọ́, èmi ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí mi lọ́wọ́.