Job 11:13-18
Job 11:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi iwọ ba tun ọkàn rẹ ṣe, ti iwọ si nawọ rẹ sọdọ rẹ̀. Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọ̀na jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa kó wà ninu agọ rẹ. Nigbana ni iwọ o gbe oju rẹ soke laini abawọn, ani iwọ o duro ṣinṣin, iwọ kì yio si bẹ̀ru. Nitoripe iwọ o gbagbe òṣi rẹ, iwọ o si ranti rẹ̀ bi omi ti o ti ṣàn kọja lọ. Ọjọ aiye rẹ yio si mọlẹ jù ọsan gangan lọ, bi okunkun tilẹ bò ọ mọlẹ nisisiyi, iwọ o dabi owurọ̀. Iwọ o si wà lailewu, nitoripe ireti wà, ani iwọ o rin ilẹ rẹ wò, iwọ o si simi li alafia.
Job 11:13-18 Yoruba Bible (YCE)
“Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́, o óo lè nawọ́ sí i. Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ. Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi; o óo wà láìléwu, o kò sì ní bẹ̀rù. O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ, nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀, yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ. Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ; òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀. Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí, a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu.
Job 11:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù, tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù, Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ, ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ. Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀. Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.