Job 1:5 - Compare All Versions

Job 1:5 YBCV (Bibeli Mimọ)

O si ṣe, nigbati ọjọ àse wọn pé yika, ni Jobu ranṣẹ lọ iyà wọn si mimọ, o si dide ni kùtukutu owurọ, o si rú ẹbọ sisun niwọn iye gbogbo wọn; nitoriti Jobu wipe: bọya awọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, nwọn kò si ṣọpẹ́ fun Ọlọrun lọkàn wọn. Bẹ̃ni Jobu imaṣe nigbagbogbo.

Job 1:5 YCE (Yoruba Bible)

Nígbà tí wọ́n bá se àsè náà kárí tán, Jobu yóo ranṣẹ sí wọn láti rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún wọn. Ní àárọ̀ kutukutu, yóo dìde yóo rú ẹbọ sísun fún olukuluku wọn, yóo wí pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti bú Ọlọrun ninu ọkàn wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Jobu máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà.

Job 1:5 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.