Job 1:1-5
Job 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌKUNRIN kan wà ni ilẹ Usi, orukọ ẹniti ijẹ Jobu; ọkunrin na si ṣe olõtọ, o duro ṣinṣin, ẹniti o si bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu. A si bi ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta fun u. Ohunọ̀sin rẹ̀ si jẹ ẹdẹgbarin agutan, ati ẹgbẹdogun ibakasiẹ, ati ẹdẹgbẹta ajaga ọdámalu, ati ẹdẹgbẹta abokẹtẹkẹtẹ, o si pọ̀; bẹ̃li ọkunrin yi si pọ̀ jù gbogbo awọn ọmọ ara ila-õrun lọ. Awọn ọmọ rẹ̀ a si ma lọ ijẹun àse ninu ile ara wọn, olukuluku li ọjọ rẹ̀; nwọn a si ma ranṣẹ pe arabinrin wọn mẹtẹta lati jẹun ati lati mu pẹlu wọn. O si ṣe, nigbati ọjọ àse wọn pé yika, ni Jobu ranṣẹ lọ iyà wọn si mimọ, o si dide ni kùtukutu owurọ, o si rú ẹbọ sisun niwọn iye gbogbo wọn; nitoriti Jobu wipe: bọya awọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, nwọn kò si ṣọpẹ́ fun Ọlọrun lọkàn wọn. Bẹ̃ni Jobu imaṣe nigbagbogbo.
Job 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jobu; ó ń gbé ilẹ̀ Usi, ó jẹ́ olódodo ati olóòótọ́ eniyan, ó bẹ̀rù Ọlọrun, ó sì kórìíra ìwà burúkú. Ó bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. Ó ní ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan, ẹgbẹẹdogun (3,000) ràkúnmí, ẹẹdẹgbẹta (500) àjàgà mààlúù, ẹẹdẹgbẹta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ọpọlọpọ iranṣẹ; òun ni ó lọ́lá jùlọ ninu gbogbo àwọn ará ìlà oòrùn. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa lọ jẹ àsè ninu ilé ara wọn. Olukuluku wọn ní ọjọ́ àsè tirẹ̀, wọn a sì máa pe àwọn arabinrin wọn wá sí ilé láti bá wọn jẹ àsè. Nígbà tí wọ́n bá se àsè náà kárí tán, Jobu yóo ranṣẹ sí wọn láti rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún wọn. Ní àárọ̀ kutukutu, yóo dìde yóo rú ẹbọ sísun fún olukuluku wọn, yóo wí pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti bú Ọlọrun ninu ọkàn wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Jobu máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà.
Job 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú, A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ. Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.