Joh 4:39-54

Joh 4:39-54 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu na wá si gbà a gbọ́, nitori ọ̀rọ obinrin na, o jẹri pe, O sọ gbogbo ohun ti mo ti ṣe fun mi. Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji. Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀; Nwọn si wi fun obinrin na pe, Ki iṣe nitori ọrọ rẹ mọ li awa ṣe gbagbọ: nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye. Lẹhin ijọ meji o si ti ibẹ̀ kuro, o lọ si Galili. Nitori Jesu tikararẹ̀ ti jẹri wipe, Woli ki ini ọlá ni ilẹ on tikararẹ̀. Nitorina nigbati o de Galili, awọn ara Galili gbà a, nitoriti nwọn ti ri ohun gbogbo ti o ṣe ni Jerusalemu nigba ajọ; nitori awọn tikarawọn lọ si ajọ pẹlu. Bẹ̃ni Jesu tún wà si Kana ti Galili, nibiti o gbé sọ omi di waini. Ọkunrin ọlọla kan si wà, ẹniti ara ọmọ rẹ̀ kò da ni Kapernaumu. Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Judea wá si Galili, o tọ̀ ọ wá, o si mbẹ̀ ẹ, ki o le sọkalẹ wá ki o mu ọmọ on larada: nitoriti o wà li oju ikú. Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Bikoṣepe ẹnyin ba ri àmi ati iṣẹ iyanu, ẹnyin kì yio gbagbọ́ lai. Ọkunrin ọlọla na wi fun u pe, Oluwa, sọkalẹ wá, ki ọmọ mi ki o to ku. Jesu wi fun u pe, Mã ba ọ̀na rẹ lọ; ọmọ rẹ yè. Ọkunrin na si gbà ọ̀rọ ti Jesu sọ fun u gbọ́, o si lọ. Bi o si ti nsọkalẹ lọ, awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pade rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, ọmọ rẹ yè. Nigbana li o bère wakati ti o bẹ̀rẹ si isàn lọwọ wọn. Nwọn si wi fun u pe, Li ana, ni wakati keje, ni ibà na fi i silẹ. Bẹ̃ni baba na mọ̀ pe, ni wakati kanna ni, ninu eyi ti Jesu wi fun u pe, Ọmọ rẹ yè: on tikararẹ̀ si gbagbọ́, ati gbogbo ile rẹ̀. Eyi ni iṣẹ́ ami keji, ti Jesu ṣe nigbati o ti Judea jade wá si Galili.

Joh 4:39-54 Yoruba Bible (YCE)

Ọpọlọpọ ninu àwọn ará Samaria tí ó wá láti inú ìlú gbà á gbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ obinrin tí ó jẹ́rìí pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.” Nígbà tí àwọn ará Samaria dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Ó bá dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meji. Ọpọlọpọ àwọn mìíràn tún gbàgbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n wí fún obinrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ohun tí o sọ ni a fi gbàgbọ́, nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, a wá mọ̀ nítòótọ́ pé òun ni Olùgbàlà aráyé.” Lẹ́yìn ọjọ́ meji, Jesu jáde kúrò níbẹ̀ lọ sí Galili. Nítorí òun fúnrarẹ̀ jẹ́rìí pé, “Wolii kan kò ní ọlá ninu ìlú baba rẹ̀.” Nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, nítorí pé àwọn náà lọ sí ibi àjọ̀dún náà. Jesu tún lọ sí ìlú Kana ti Galili níbi tí ó ti sọ omi di ọtí ní ìjelòó. Ìjòyè kan wà ní Kapanaumu tí ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ. Jesu wí fún un pé, “Bí ẹ kò bá rí iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu ẹ kò ní gbàgbọ́.” Ìjòyè náà bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, tètè wá kí ọmọ mi tó kú.” Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ọmọ rẹ yóo yè.” Ọkunrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un gbọ́, ó bá ń lọ sílé. Bí ó ti ń lọ, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá pàdé rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Ọmọ rẹ ti gbádùn.” Ìjòyè náà wádìí lọ́wọ́ wọn nípa àkókò tí ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Lánàá, ní nǹkan bí aago kan ni ibà náà lọ.” Baba ọmọ náà mọ̀ pé àkókò náà gan-an ni Jesu sọ fún òun pé, “Ọmọ rẹ yóo yè.” Òun ati gbogbo ilé rẹ̀ bá gba Jesu gbọ́. Èyí ni iṣẹ́ abàmì keji tí Jesu ṣe nígbà tí ó kúrò ní Judia, tí ó wá sí Galili.

Joh 4:39-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.” Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.” Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Galili. Nítorí Jesu tìkára rẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ òun tìkára rẹ̀. Nítorí náà nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jerusalẹmu nígbà àjọ ìrékọjá; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú. Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.” Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.” Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.” Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀. Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.