Joh 2:1-10
Joh 2:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
NI ijọ kẹta a si nṣe igbeyawo kan ni Kana ti Galili; iya Jesu si mbẹ nibẹ̀: A si pè Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu, si ibi igbeyawo. Nigbati waini si tan, iya Jesu wi fun u pe, Nwọn kò ni waini. Jesu wi fun u pe, Kini ṣe temi tirẹ, obinrin yi? wakati mi kò iti de. Iya rẹ̀ wi fun awọn iranṣẹ pe, Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e. Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti. O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ. Bi olori àse si ti tọ́ omi ti a sọ di waini wò, ti ko si mọ̀ ibi ti o ti wá (ṣugbọn awọn iranṣẹ ti o bù omi na wá mọ̀), olori àse pè ọkọ iyawo, O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi.
Joh 2:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ń ṣe igbeyawo kan ní Kana, ìlú kan ní Galili. Ìyá Jesu wà níbẹ̀. Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà. Nígbà tí ọtí tán, ìyá Jesu sọ fún un pé, “Wọn kò ní ọtí mọ́!” Jesu wí fún un pé, “Kí ni tèmi ati tìrẹ ti jẹ́, obinrin yìí? Àkókò mi kò ì tíì tó.” Ìyá rẹ̀ sọ fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ ṣe ohunkohun tí ó bá wí fun yín.” Ìkòkò òkúta mẹfa kan wà níbẹ̀, tí wọ́n ti tọ́jú fún omi ìwẹ-ọwọ́-wẹ-ẹsẹ̀ àwọn Juu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó bíi garawa omi marun-un tabi mẹfa. Jesu wí fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìkòkò wọnyi.” Wọ́n bá pọnmi kún wọn. Ó bá tún wí fún wọn pé, “Ẹ bù ninu rẹ̀ lọ fún alága àsè.” Wọ́n bá bù ú lọ. Nígbà tí alága àsè tọ́ omi tí ó di ọtí wò, láì mọ ibi tí ó ti wá, (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iranṣẹ tí ó bu omi náà mọ̀), alága àsè pe ọkọ iyawo. Ó ní, “Ọtí tí ó bá dùn ni gbogbo eniyan kọ́ ń gbé kalẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan bá ti mu ọtí yó tán, wọn á wá gbé ọtí èyí tí kò dára tóbẹ́ẹ̀ wá. Ṣugbọn ìwọ fi àtàtà ọtí yìí pamọ́ di àkókò yìí!”
Joh 2:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀, A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà. Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.” Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.” Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.” Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá. Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí. Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.” Wọ́n sì gbé e lọ; alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan, Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”