Joh 17:6-19
Joh 17:6-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Nisisiyi nwọn mọ̀ pe, ohunkohun gbogbo ti iwọ ti fifun mi, lati ọdọ rẹ wá ni. Nitori ọ̀rọ ti iwọ fifun mi, emi ti fifun wọn, nwọn si ti gbà a, nwọn si ti mọ̀ nitõtọ pe, lọdọ rẹ ni mo ti jade wá, nwọn si gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. Emi ngbadura fun wọn: emi kò gbadura fun araiye, ṣugbọn fun awọn ti iwọ ti fifun mi; nitoripe tirẹ ni nwọn iṣe. Tirẹ sá ni gbogbo ohun ti iṣe temi, ati temi si ni gbogbo ohun ti iṣe tirẹ; a si ti ṣe mi logo ninu wọn. Emi kò si si li aiye mọ́, awọn wọnyi si mbẹ li aiye, emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ. Baba mimọ́, pa awọn ti o ti fifun mi mọ́, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, ani gẹgẹ bi awa. Nigbati mo wà pẹlu wọn li aiye, mo pa wọn mọ li orukọ rẹ: awọn ti iwọ fifun mi, ni mo ti pamọ́, ẹnikan ninu wọn kò si ṣègbe bikoṣe ọmọ egbé; ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ. Ṣugbọn nisisiyi emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ, nkan wọnyi ni mo si nsọ li aiye, ki nwọn ki o le ni ayọ̀ mi ni kikun ninu awọn tikarawọn. Emi ti fi ọ̀rọ rẹ fun wọn; aiye si ti korira wọn, nitoriti nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì iti iṣe ti aiye. Emi ko gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro li aiye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ́ kuro ninu ibi. Nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì ti iṣe ti aiye. Sọ wọn di mimọ́ ninu otitọ: otitọ li ọ̀rọ rẹ. Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si aiye, bẹ̃ li emi si rán wọn si aiye pẹlu. Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ.

Joh 17:6-19 Yoruba Bible (YCE)
“Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Nisinsinyii ó ti yé wọn pé láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo tí o fún mi ti wá. Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. “Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n. Ohun gbogbo tí mo ní, tìrẹ ni; ohun gbogbo tí ìwọ náà sì ní, tèmi ni. Wọ́n ti jẹ́ kí ògo mi yọ. Èmi kò ní sí ninu ayé mọ́, ṣugbọn àwọn wà ninu ayé. Èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, mo fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́. Mo pa wọ́n mọ́, ọ̀kan ninu wọn kò ṣègbé àfi ọmọ ègbé, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ. Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé. N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé. Fi òtítọ́ yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti rán mi sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni mo rán wọn lọ sinu ayé. Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́.
Joh 17:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá: tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Nísinsin yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni. Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi. Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe. Tìrẹ sá à ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn. Èmi kò sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa. Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn. Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́.