Joh 17:14-19
Joh 17:14-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ti fi ọ̀rọ rẹ fun wọn; aiye si ti korira wọn, nitoriti nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì iti iṣe ti aiye. Emi ko gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro li aiye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ́ kuro ninu ibi. Nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì ti iṣe ti aiye. Sọ wọn di mimọ́ ninu otitọ: otitọ li ọ̀rọ rẹ. Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si aiye, bẹ̃ li emi si rán wọn si aiye pẹlu. Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ.
Joh 17:14-19 Yoruba Bible (YCE)
Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé. N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé. Fi òtítọ́ yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí o ti rán mi sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni mo rán wọn lọ sinu ayé. Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́.
Joh 17:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́.