Joh 14:7-14
Joh 14:7-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i. Filippi wi fun u pe, Oluwa, fi Baba na hàn wa, o si to fun wa. Jesu wi fun u pe, Bi akokò ti mo ba nyin gbé ti pẹ to yi, iwọ kò si ti imọ̀ mi sibẹ̀ Filippi? Ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wipe, Fi Baba hàn wa? Iwọ kò ha gbagbọ́ pe, Emi wà ninu Baba, ati pe Baba wà ninu mi? ọ̀rọ ti emi nsọ fun nyin, emi kò da a sọ; ṣugbọn Baba ti ngbé inu mi, on ni nṣe iṣẹ rẹ̀. Ẹ gbà mi gbọ́ pe, emi wà ninu Baba, Baba si wà ninu mi: bikoṣe bẹ̃, ẹ gbà mi gbọ́ nitori awọn iṣẹ na pãpã. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba. Ohunkohun ti ẹnyin ba si bère li orukọ mi, on na li emi ó ṣe, ki a le yìn Baba logo ninu Ọmọ. Bi ẹnyin ba bère ohunkohun li orukọ mi, emi ó ṣe e.
Joh 14:7-14 Yoruba Bible (YCE)
Bí ẹ bá ti mọ̀ mí, ẹ óo mọ Baba mi. Láti àkókò yìí, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.” Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.” Jesu wí fún un pé, “Bí mo ti pẹ́ lọ́dọ̀ yín tó yìí, sibẹ ìwọ kò mọ̀ mí, Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi ti rí Baba. Kí ló dé tí o fi tún ń sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá?’ Àbí o kò gbàgbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi ni? Èmi fúnra mi kọ́ ni mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fun yín. Baba tí ó ń gbé inú mi ni ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí iṣẹ́ wọnyi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba. Èmi yóo ṣe ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi, kí ògo Baba lè yọ lára Ọmọ. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ mi ní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é.
Joh 14:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.” Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.” Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba: Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’ Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi: bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá! Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba. Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ. Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.