Joh 14:5-7
Joh 14:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na? Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi. Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i.
Joh 14:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Tomasi wí fún un pé, “Oluwa, a kò mọ ibi tí ò ń lọ, báwo ni a ti ṣe lè mọ ọ̀nà ibẹ̀?” Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi. Bí ẹ bá ti mọ̀ mí, ẹ óo mọ Baba mi. Láti àkókò yìí, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”
Joh 14:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tomasi wí fún un pé, “Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”