Joh 14:1-10

Joh 14:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú: ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú. Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà: ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín. Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.” Tomasi wí fún un pé, “Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.” Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.” Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba: Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’ Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

Joh 14:1-10

Joh 14:1-10 YBCVJoh 14:1-10 YBCVJoh 14:1-10 YBCVJoh 14:1-10 YBCVJoh 14:1-10 YBCV