Joh 11:32-33
Joh 11:32-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú. Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ
Joh 11:32-33 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.” Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́.
Joh 11:32-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.” Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́.