Joh 1:4-9
Joh 1:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye. Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀. Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu. On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀. On kì iṣe imọlẹ̀ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na. Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.
Joh 1:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé. Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀. Ọkunrin kan wà tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johanu. Òun ni ó wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kí ó lè jẹ́rìí sí ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo eniyan lè torí ẹ̀rí rẹ̀ gbàgbọ́. Kì í ṣe òun ni ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn ó wá láti jẹ́rìí ìmọ́lẹ̀ náà. Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé.
Joh 1:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé, ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀. Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Johanu. Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀. Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà. Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé.