Jer 9:3-9
Jer 9:3-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi. Ẹ mã ṣọra, olukuluku nyin lọdọ aladugbo rẹ̀, ki ẹ má si gbẹkẹle arakunrin karakunrin: nitoripe olukuluku arakunrin fi arekereke ṣẹtan patapata, ati olukuluku aladugbo nsọ̀rọ ẹnilẹhin. Ẹnikini ntàn ẹnikeji rẹ̀ jẹ, nwọn kò si sọ otitọ: nwọn ti kọ́ ahọn wọn lati ṣeke, nwọn si ti ṣe ara wọn lãrẹ lati ṣe aiṣedede. Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, emi o yọ́ wọn, emi o si dán wọn wò, nitori kili emi o ṣe fun ọmọbinrin enia mi. Ahọn wọn dabi ọfa ti a ta, o nsọ ẹ̀tan, ẹnikini nfi ẹnu rẹ̀ sọ alafia fun ẹnikeji rẹ̀, ṣugbọn li ọkàn rẹ̀ o ba dè e. Emi kì yio ha bẹ̀ wọn wò nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ọkàn mi kì yio ha gbẹsan lara orilẹ-ède bi iru eyi?
Jer 9:3-9 Yoruba Bible (YCE)
Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn, láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà; dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà. OLUWA ní, “Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi, wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.” Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan. Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin, a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò. Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́. Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa; wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn, wọn kò sì ronú àtipàwàdà. Ìninilára ń gorí ìninilára, ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn, OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.” Nítorí náà, ó ní: “Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́, n óo dán wọn wò. Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí? Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀, ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi? Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?”
Jer 9:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òtítọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn; wọn kò sì náání mi, ní OLúWA wí. Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ. Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́. Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn, ni OLúWA wí. Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi? Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró ó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀; ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀. Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?” ni OLúWA wí. “Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”