Jer 9:10-24
Jer 9:10-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Fun awọn oke-nla ni emi o gbe ẹkún ati ohùnrere soke, ati ẹkún irora lori papa oko aginju wọnnì, nitoriti nwọn jona, ẹnikan kò le kọja nibẹ, bẹ̃ni a kò gbọ́ ohùn ẹran-ọsin, lati ẹiyẹ oju-ọrun titi de ẹranko ti sa kuro, nwọn ti lọ. Emi o sọ Jerusalemu di okiti àlapa, ati iho awọn ikõko, emi o si sọ ilu Juda di ahoro, laini olugbe. Tani enia na ti o gbọ́n, ti o moye yi? ati tani ẹniti ẹnu Oluwa ti sọ fun, ki o ba le kede rẹ̀, pe: kili o ṣe ti ilẹ fi ṣegbe, ti o si sun jona bi aginju, ti ẹnikan kò kọja nibẹ? Oluwa si wipe, nitoriti nwọn ti kọ̀ ofin mi silẹ ti mo ti gbe kalẹ niwaju wọn, ti nwọn kò si gbà ohùn mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò si rin ninu rẹ̀. Ṣugbọn nwọn ti rin nipa agidi ọkàn wọn ati nipasẹ Baalimu, ti awọn baba wọn kọ́ wọn: Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi; sa wò o, awọn enia yi pãpa ni emi o fi wahala bọ́, emi o si mu wọn mu omi orõro. Emi o si tú wọn ka ninu awọn keferi, ti awọn tikarawọn ati baba wọn kò mọ ri, emi o si rán idà si wọn titi emi o fi run wọn. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá. Ki nwọn ki o si yara, ki nwọn pohùnrere ẹkun fun wa, ki oju wa ki o le sun omije ẹkun, ati ki ipenpeju wa le tu omi jade. Nitori a gbọ́ ohùn ẹkun lati Sioni, pe, A ti pa wa run to! awa dãmu jọjọ, nitoriti a kọ̀ ilẹ yi silẹ, nitoriti ibugbe wa tì wa jade. Njẹ ẹnyin obinrin, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹ jẹ ki eti nyin gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀, ki ẹ si kọ́ ọmọbinrin nyin ni ẹkun, ati ki olukuluku obinrin ki o kọ́ aladugbo rẹ̀ ni arò. Nitori iku ti de oju ferese wa, o ti wọ̀ inu ãfin wa, lati ke awọn ọmọ-ọmu kuro ni ita, ati awọn ọmọdekunrin kuro ni igboro. Sọ pe, Bayi li Oluwa wi, Okú enia yio ṣubu bi àtan li oko, ati bi ibukunwọ lẹhin olukore, ti ẹnikan ko kojọ. Bayi li Oluwa wi, ki ọlọgbọ́n ki o má ṣogo nitori ọgbọ́n rẹ̀, bẹ̃ni ki alagbara ki o má ṣogo nitori agbara rẹ̀, ki ọlọrọ̀ ki o má ṣogo nitori ọrọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yio ba ma ṣogo, ki o ṣe e ninu eyi pe: on ni oye, on si mọ̀ mi; pe, Emi li Oluwa ti nṣe ãnu ati idajọ ati ododo li aiye: nitori inu mi dùn ninu ohun wọnyi, li Oluwa wi.
Jer 9:10-24 Yoruba Bible (YCE)
Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀, nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá. A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀. Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.” OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Mo bá bèèrè pé, “Ta ni ẹni tí ó gbọ́n, tí òye nǹkan yìí yé? Ta ni OLUWA ti bá sọ̀rọ̀, kí ó kéde rẹ̀? Kí ló dé tí ilẹ̀ náà fi parun, tí ó sì dàbí aṣálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò fi gba ibẹ̀ kọjá?” OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn. Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá, ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára; kí wọ́n wá kíá, kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí, kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò. Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni, wọ́n ń ké pé, ‘A gbé! Ìtìjú ńlá dé bá wa, a níláti kó jáde nílé, nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ” Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun, kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò. Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa, ó ti wọ ààfin wa. Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro, ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.” Sọ wí pé, “Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú, ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà, kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀, kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀; kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu, ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òye ati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́, tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé; nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.”
Jer 9:10-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì. Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ. “Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì àlàpà àti ihò àwọn ìkookò. Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.” Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni OLúWA ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá? OLúWA sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn. Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé. Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.” Èyí sì ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá; sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn. Jẹ́ kí wọn wá kíákíá, kí wọn wá pohùnréré ẹkún lé wa lórí títí ojú wa yóò fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa A gbọ́ igbe ìpohùnréré ẹkún ní Sioni: ‘Àwa ti ṣègbé tó! A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ” Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA. Ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò. Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé ó sì ti wọ odi alágbára wa ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba. Sọ pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú bí ààtàn ní oko gbangba àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ” Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, èmi ni OLúWA tí ń ṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodo ní ayé nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” OLúWA wí.