Jer 8:4-19

Jer 8:4-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; enia le ṣubu li aidide mọ? tabi enia le pada, ki o má tun yipada mọ? Ẽṣe ti awọn enia Jerusalemu yi sọ ipadasẹhin di ipẹhinda lailai? nwọn di ẹ̀tan mu ṣinṣin, nwọn kọ̀ lati pada. Mo tẹti lélẹ, mo si gbọ́, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ titọ: kò si ẹnikan ti o ronupiwada buburu rẹ̀ wipe, kili emi ṣe? gbogbo nwọn yipo li ọ̀na wọn, bi akọ-ẹṣin ti nsare gburu sinu ogun. Lõtọ ẹiyẹ àkọ li oju-ọrun mọ̀ akoko rẹ̀, àdaba ati ẹiyẹ lekeleke pẹlu alapandẹ̀dẹ sọ́ igba wiwá wọn; ṣugbọn enia mi kò mọ̀ idajọ Oluwa. Bawo li ẹnyin ṣe wipe, Ọlọgbọ́n ni wa, ati ofin Oluwa mbẹ lọdọ wa? sa wò o nitõtọ! kalamu eke awọn akọwe ti sọ ofin di eke. Oju tì awọn ọlọgbọ́n, idamu ba wọn a si mu wọn: sa wò o, nwọn ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa! ọgbọ́n wo li o wà ninu wọn? Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan. Nitoripe nwọn ti wo ipalara ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀ wipe, Alafia! Alafia! nigbati alafia kò si. Itiju yio ba wọn nitori nwọn ti ṣe ohun irira, sibẹ nwọn kò tiju, bẹ̃ni õru itiju kò mu wọn, nitorina ni nwọn o ṣe ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu; ni igba ibẹ̀wo wọn, a o si wó wọn lulẹ, li Oluwa wi. Ni kiká emi o ká wọn jọ, li Oluwa wi, eso-àjara kì yio si mọ lori ajara, tabi eso-ọ̀pọtọ lori igi ọ̀pọtọ, ewe rẹ̀ yio si rẹ̀; nitorina ni emi o yàn awọn ti yio kọja lọ lori rẹ̀. Ẽṣe ti awa joko jẹ? ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si jẹ ki a wọ̀ inu ilu olodi, ki a si dakẹ sibẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wa, ti mu wa dakẹ, o si fun wa ni omi orõro lati mu, nitori ti awa ṣẹ̀ si Oluwa. Awa reti alafia, ṣugbọn kò si ireti kan, ati ìgba didá ara, si kiye si i, idamu! Lati Dani ni a gbọ́ fifọn imu ẹṣin rẹ̀; gbogbo ilẹ warìri fun iro yiyan akọ-ẹṣin rẹ̀; nwọn si de, nwọn si jẹ ile run, ati eyi ti mbẹ ninu rẹ̀: ilu ati awọn ti ngbe inu rẹ̀, Sa wò o, emi o ran ejo, ejo gunte si ãrin nyin, ti kì yio gbọ́ ituju, nwọn o si bu nyin jẹ, li Oluwa wi. Emi iba le tù ara mi ninu, ninu ikãnu mi? ọkàn mi daku ninu mi! Sa wò o, ohùn ẹkún ọmọbinrin enia mi, lati ilẹ jijina wá, Kò ha si Oluwa ni Sioni bi? ọba rẹ̀ kò ha si ninu rẹ̀? ẽṣe ti nwọn fi ere gbigbẹ ati ohun asan àjeji mu mi binu?

Jer 8:4-19 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “Ṣé bí eniyan bá ṣubú kì í tún dìde mọ́? Àbí bí eniyan bá ṣìnà, kì í pada mọ́? Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn? Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́; wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi. Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn, ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere. Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀, kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’ Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú, bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun. Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀; wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada. Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA. Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé, ‘Ọlọ́gbọ́n ni wá, a sì mọ òfin OLUWA?’ Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké. Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n: ìdààmú yóo bá wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n. Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀, ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n? Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn, n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn. Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù, títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù. Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná, wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’ bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia. Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n, nítorí pé wọn kò lójútì. Nítorí náà àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú, a óo bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. “Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí, àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ, ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé, “Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ, kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi, kí á sì parun sibẹ; nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́, ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu, nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́. À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé. Àkókò ìwòsàn ni à ń retí, ṣugbọn ìpayà ni a rí. Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani; gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn. Wọ́n wá run ilẹ̀ náà, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.” OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín: paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn; wọn yóo sì bù yín jẹ.” Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn, àárẹ̀ mú ọkàn mi. Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mi jákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé, “Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni? Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”

Jer 8:4-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí? Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti yípadà. Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun. Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí OLúWA wọn fẹ́. “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n, nítorí a ní òfin OLúWA,” nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn. Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn. Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLúWA, irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní? Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn. Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀. “Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí, nígbà tí kò sí àlàáfíà. Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú, a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò, ni OLúWA wí. “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò, ni OLúWA wí. Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà. Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ” “Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí? A kó ara wa jọ! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi kí a sì ṣègbé síbẹ̀. Nítorí tí OLúWA Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu, nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i. Àwa ń retí àlàáfíà kò sí ìre kan, tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá bí kò ṣe ìpayà nìkan. Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ń gbọ́ láti Dani, yíyan àwọn akọ ẹṣin mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀. “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni OLúWA wí. Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi, rẹ̀wẹ̀sì nínú mi. Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá: “OLúWA kò ha sí ní Sioni bí? Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”