Jer 7:16-29
Jer 7:16-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina máṣe gbadura fun enia yi, bẹ̃ni ki o má si gbe igbe rẹ soke ati adura fun wọn, bẹ̃ni ki o má ṣe rọ̀ mi: nitori emi kì yio gbọ́ tirẹ. Iwọ kò ha ri ohun ti nwọn nṣe ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu? Awọn ọmọ ko igi jọ, awọn baba nda iná, awọn obinrin npò akara lati ṣe akara didùn fun ayaba-ọrun ati lati tú ẹbọ-ọrẹ mimu jade fun ọlọrun miran, ki nwọn ki o le rú ibinu mi soke. Ibinu mi ni nwọn ha ru soke bi? li Oluwa wi, kì ha ṣe si ara wọn fun rudurudu oju wọn? Nitorina bayi li Ọlọrun Oluwa wi, sa wò o, a o dà ibinu ati irunu mi si ibi yi, sori enia ati sori ẹranko, ati sori igi igbo, ati sori eso ilẹ, yio si jo, a kì o le pa iná rẹ̀. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, kó ẹbọ sisun nyin pẹlu ẹbọ jijẹ nyin, ki ẹ si jẹ ẹran. Nitori emi kò wi fun awọn baba nyin, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn ni ọjọ ti mo mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti niti ẹbọ sisun tabi ẹbọ jijẹ: Ṣugbọn eyi ni mo paṣẹ fun wọn wipe, Gba ohùn mi gbọ́, emi o si jẹ Ọlọrun nyin, ẹnyin o si jẹ enia mi: ki ẹ si rin ni gbogbo ọ̀na ti mo ti paṣẹ fun nyin, ki o le dara fun nyin. Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹ eti silẹ, nwọn si rin ni ìmọ ati agidi ọkàn buburu wọn, nwọn si kọ̀ ẹ̀hin wọn kì iṣe oju wọn si mi. Lati ọjọ ti baba nyin ti ti ilẹ Egipti jade wá titi di oni, emi ti rán gbogbo iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, lojojumọ emi dide ni kutukutu, emi si rán wọn. Sibẹ nwọn kò gbọ́ temi, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ, sugbọn nwọn mu ọrun le, nwọn ṣe buburu jù awọn baba wọn lọ. Bi iwọ ba si wi gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, nwọn kì yio gbọ́ tirẹ: iwọ o si pè wọn, ṣugbọn nwọn kì o da ọ lohùn. Iwọ o si wi fun wọn pe: Eyi ni enia na ti kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò gba ẹkọ́: otitọ ṣègbe, a si ke e kuro li ẹnu wọn. Fá irun ori rẹ, ki o si sọ ọ nù, ki o si sọkun lori oke: nitori Oluwa ti kọ̀ iran ibinu rẹ̀ silẹ, o si ṣa wọn tì.
Jer 7:16-29 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ìwọ Jeremaya ní tìrẹ, má bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan wọnyi, má sọkún nítorí wọn, tabi kí o gbadura fún wọn. Má sì bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí n kò ní gbọ́. Ṣé o kò rí àwọn ohun tí wọn ń ṣe ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu ni? Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn baba wọn ń dá iná, àwọn obinrin ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà fún Ayaba Ọ̀run. Wọ́n sì ń ta ọtí sílẹ̀ fún àwọn oriṣa láti mú mi bínú. Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn? Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo tú ibinu gbígbóná mi sórí ibí yìí, n óo bínú sí eniyan ati ẹranko, ati igi oko ati èso ilẹ̀. Ibinu mi óo jó wọn run bí iná, kò sì ní ṣe é pa. “Ẹ da ẹbọ sísun yín pọ̀ mọ́ ẹran tí ẹ fi rúbọ, kí ẹ lè rí ẹran jẹ; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí ní ọjọ́ tí mo kó àwọn baba yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, n kò bá wọn sọ̀rọ̀ ẹbọ sísun tabi ẹbọ rírú, bẹ́ẹ̀ ni n kò pàṣẹ rẹ̀ fún wọn. Àṣẹ tí mo pa fún wọn ni pé kí wọn gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ní n óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà óo sì máa jẹ́ eniyan mi; mo ní kí wọn máa tọ ọ̀nà tí mo bá pa láṣẹ fún wọn, kí ó lè dára fún wọn. Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì tẹ́tí sí mi. Wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn, wọ́n ń ṣe oríkunkun, dípò kí wọ́n máa lọ siwaju, ẹ̀yìn ni wọ́n ń pada sí. Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní ilẹ̀ Ijipti títí di òní, lojoojumọ ni mò ń rán àwọn wolii iranṣẹ mi sí wọn léraléra. Sibẹ wọn kò gbọ́ tèmi, wọn kò tẹ́tí sí mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, oríkunkun ni wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ burúkú wọn ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ. “Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn. O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’ “Ẹ gé irun orí yín dànù, ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè, nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀, ó ti fi ibinu ta ìran yín nù.
Jer 7:16-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ. Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè. Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni OLúWA wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn? “ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí, “Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èso orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.” “ ‘Èyí ni OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnra yín. Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán. Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé; gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn. Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Ejibiti títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín. Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’ “Nígbà tí ìwọ bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn. Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ti OLúWA Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn. “ ‘Gé irun yín kí ẹ sì dàánù, pohùnréré ẹkún lórí òkè, nítorí OLúWA ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀.