Jer 7:1-34

Jer 7:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá wipe: Duro ni ẹnu ilẹkun ile Oluwa, ki o si kede ọ̀rọ yi wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin ti Juda ti ẹ wọ̀ ẹnu ilẹkun wọnyi lati sin Oluwa. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe, emi o si jẹ ki ẹnyin ma gbe ibi yi. Ẹ máṣe gbẹkẹle ọ̀rọ eke, wipe: Tempili Oluwa, Tempili Oluwa, Tempili Oluwa ni eyi! Nitori bi ẹnyin ba tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe nitõtọ; ti ẹnyin ba ṣe idajọ otitọ jalẹ, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀. Ti ẹnyin kò ba si ṣẹ́ alejo ni iṣẹ́, alainibaba ati opó, ti ẹnyin kò si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ni ibi yi, ti ẹnyin kò si rìn tọ ọlọrun miran si ipalara nyin. Nigbana ni emi o mu nyin gbe ibi yi, ni ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin lai ati lailai. Sa wò o, ẹnyin gbẹkẹle ọ̀rọ eke, ti kò ni ère. Kohaṣepe, ẹnyin njale, ẹ npania, ẹ nṣe panṣaga, ẹ nbura eke, ẹ nsun turari fun Baali, ẹ si nrin tọ ọlọrun miran ti ẹnyin kò mọ̀? Ẹnyin si wá, ẹ si duro niwaju mi ni ile yi, ti a fi orukọ mi pè! ẹnyin si wipe: Gbà wa, lati ṣe gbogbo irira wọnyi? Ile yi, ti ẹ fi orukọ mi pè, o ha di iho olè li oju nyin? sa wò o, emi tikarami ti ri i, li Oluwa wi. Ẹ si lọ nisisiyi, si ibujoko mi, ti o wà ni Ṣilo, ni ibi ti emi fi orukọ mi si li àtetekọṣe, ki ẹ si ri ohun ti emi ṣe si i nitori ìwa-buburu enia mi, Israeli. Njẹ nisisiyi, nitori ẹnyin ti ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi, li Oluwa wi, ti emi si ba nyin sọ̀rọ, ti emi ndide ni kutukutu ti mo si nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́; ti emi si npè nyin, ṣugbọn ẹnyin kò dahùn. Nitorina li emi o ṣe si ile yi, ti a pè ni orukọ mi, ti ẹ gbẹkẹle, ati si ibi ti emi fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin, gẹgẹ bi emi ti ṣe si Ṣilo. Emi o si ṣá nyin tì kuro niwaju mi, gẹgẹ bi mo ti ṣá awọn arakunrin nyin tì, ani gbogbo iru-ọmọ Efraimu. Nitorina máṣe gbadura fun enia yi, bẹ̃ni ki o má si gbe igbe rẹ soke ati adura fun wọn, bẹ̃ni ki o má ṣe rọ̀ mi: nitori emi kì yio gbọ́ tirẹ. Iwọ kò ha ri ohun ti nwọn nṣe ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu? Awọn ọmọ ko igi jọ, awọn baba nda iná, awọn obinrin npò akara lati ṣe akara didùn fun ayaba-ọrun ati lati tú ẹbọ-ọrẹ mimu jade fun ọlọrun miran, ki nwọn ki o le rú ibinu mi soke. Ibinu mi ni nwọn ha ru soke bi? li Oluwa wi, kì ha ṣe si ara wọn fun rudurudu oju wọn? Nitorina bayi li Ọlọrun Oluwa wi, sa wò o, a o dà ibinu ati irunu mi si ibi yi, sori enia ati sori ẹranko, ati sori igi igbo, ati sori eso ilẹ, yio si jo, a kì o le pa iná rẹ̀. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, kó ẹbọ sisun nyin pẹlu ẹbọ jijẹ nyin, ki ẹ si jẹ ẹran. Nitori emi kò wi fun awọn baba nyin, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn ni ọjọ ti mo mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti niti ẹbọ sisun tabi ẹbọ jijẹ: Ṣugbọn eyi ni mo paṣẹ fun wọn wipe, Gba ohùn mi gbọ́, emi o si jẹ Ọlọrun nyin, ẹnyin o si jẹ enia mi: ki ẹ si rin ni gbogbo ọ̀na ti mo ti paṣẹ fun nyin, ki o le dara fun nyin. Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹ eti silẹ, nwọn si rin ni ìmọ ati agidi ọkàn buburu wọn, nwọn si kọ̀ ẹ̀hin wọn kì iṣe oju wọn si mi. Lati ọjọ ti baba nyin ti ti ilẹ Egipti jade wá titi di oni, emi ti rán gbogbo iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, lojojumọ emi dide ni kutukutu, emi si rán wọn. Sibẹ nwọn kò gbọ́ temi, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ, sugbọn nwọn mu ọrun le, nwọn ṣe buburu jù awọn baba wọn lọ. Bi iwọ ba si wi gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, nwọn kì yio gbọ́ tirẹ: iwọ o si pè wọn, ṣugbọn nwọn kì o da ọ lohùn. Iwọ o si wi fun wọn pe: Eyi ni enia na ti kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò gba ẹkọ́: otitọ ṣègbe, a si ke e kuro li ẹnu wọn. Fá irun ori rẹ, ki o si sọ ọ nù, ki o si sọkun lori oke: nitori Oluwa ti kọ̀ iran ibinu rẹ̀ silẹ, o si ṣa wọn tì. Nitori awọn ọmọ Juda ti ṣe buburu niwaju mi, li Oluwa wi; nwọn ti gbe ohun irira wọn kalẹ sinu ile ti a pe li orukọ mi, lati ba a jẹ. Nwọn si ti kọ́ ibi giga Tofeti, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati sun awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin wọn ninu iná; aṣẹ eyiti emi kò pa fun wọn, bẹ̃ni kò si wá si inu mi. Nitorina sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti a kì o pe e ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn a o pe e ni afonifoji ipakupa: nitori nwọn o sin oku ni Tofeti, titi àye kì yio si mọ. Okú awọn enia yi yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ: ẹnikan kì yio lé wọn kuro. Emi o si mu ki ohùn inu-didun ki o da kuro ni ilu Juda ati kuro ni ita Jerusalemu, ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ iyawo, ati ti iyawo; nitori ilẹ na yio di ahoro.

Jer 7:1-34 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA rán Jeremaya níṣẹ́, ó ní kí Jeremaya dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, kí ó sì kéde pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé láti sin OLUWA. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Ẹ tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe, kí n lè jẹ́ kí ẹ máa gbé ìhín. Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí pé: “Tẹmpili OLUWA nìyí, kò séwu, tẹmpili OLUWA nìyí.” “ ‘Bí ẹ bá tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ bá ń dá ẹjọ́ òtítọ́, tí ẹ kò bá fi ìyà jẹ àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, tabi àwọn opó, tabi kí ẹ máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì máa bọ oriṣa káàkiri, kí ẹ fi kó bá ara yín, n óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí títí lae, lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti ìgbà laelae. “ ‘Ẹ wò ó! Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò lè mú èrè wá ni ẹ gbójú lé. Ṣé ẹ fẹ́ máa jalè, kí ẹ máa pa eniyan, kí ẹ máa ṣe àgbèrè, kí ẹ máa búra èké, kí ẹ máa sun turari sí oriṣa Baali, kí ẹ máa bọ àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ káàkiri; kí ẹ sì tún máa wá jọ́sìn níwájú mi ninu ilé yìí, ilé tí à ń fi orúkọ mi pè; kí ẹ máa wí pé, “OLUWA ti gbà wá là;” kí ẹ sì tún pada lọ máa ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí ẹ tí ń ṣe? Ṣé lójú tiyín, ilé yìí, tí à ń fi orúkọ mi pè, ó ti wá di ibi ìsápamọ́ sí fún àwọn olè? Mo ti ri yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nisinsinyii, ẹ lọ sí ilé mi ní Ṣilo, níbi ìjọ́sìn mi àkọ́kọ́, kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i, nítorí ìwà burúkú Israẹli, àwọn eniyan mi. Nisinsinyii, nítorí gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe wọnyi, tí mo sì ń ba yín sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́, tí ẹ kò gbọ́, tí mo pè yín, tí ẹ kò dáhùn, bí mo ti ṣe sí Ṣilo ni n óo ṣe ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, tí ẹ gbójú lé; ati ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo le yín kúrò níwájú mi, bí mo ti lé àwọn ọmọ Efuraimu, tí wọ́n jẹ́ arakunrin yín dànù.’ ” OLUWA ní, “Ìwọ Jeremaya ní tìrẹ, má bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan wọnyi, má sọkún nítorí wọn, tabi kí o gbadura fún wọn. Má sì bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí n kò ní gbọ́. Ṣé o kò rí àwọn ohun tí wọn ń ṣe ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu ni? Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn baba wọn ń dá iná, àwọn obinrin ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà fún Ayaba Ọ̀run. Wọ́n sì ń ta ọtí sílẹ̀ fún àwọn oriṣa láti mú mi bínú. Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn? Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo tú ibinu gbígbóná mi sórí ibí yìí, n óo bínú sí eniyan ati ẹranko, ati igi oko ati èso ilẹ̀. Ibinu mi óo jó wọn run bí iná, kò sì ní ṣe é pa. “Ẹ da ẹbọ sísun yín pọ̀ mọ́ ẹran tí ẹ fi rúbọ, kí ẹ lè rí ẹran jẹ; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí ní ọjọ́ tí mo kó àwọn baba yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, n kò bá wọn sọ̀rọ̀ ẹbọ sísun tabi ẹbọ rírú, bẹ́ẹ̀ ni n kò pàṣẹ rẹ̀ fún wọn. Àṣẹ tí mo pa fún wọn ni pé kí wọn gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ní n óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà óo sì máa jẹ́ eniyan mi; mo ní kí wọn máa tọ ọ̀nà tí mo bá pa láṣẹ fún wọn, kí ó lè dára fún wọn. Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì tẹ́tí sí mi. Wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn, wọ́n ń ṣe oríkunkun, dípò kí wọ́n máa lọ siwaju, ẹ̀yìn ni wọ́n ń pada sí. Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní ilẹ̀ Ijipti títí di òní, lojoojumọ ni mò ń rán àwọn wolii iranṣẹ mi sí wọn léraléra. Sibẹ wọn kò gbọ́ tèmi, wọn kò tẹ́tí sí mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, oríkunkun ni wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ burúkú wọn ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ. “Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn. O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’ “Ẹ gé irun orí yín dànù, ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè, nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀, ó ti fi ibinu ta ìran yín nù. “Àwọn ọmọ Juda ti ṣe nǹkan burúkú. Wọ́n gbé ère wọn kalẹ̀ ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́. Wọ́n kọ́ pẹpẹ Tofeti ní àfonífojì Hinomu, wọ́n ń sun àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn níná níbẹ̀. N kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún wọn; irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ fi ìgbà kan sí lọ́kàn mi. Nítorí náà nígbà tó bá yá, a kò ní pè é ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́, àfonífojì ìpànìyàn ni a óo sì máa pè é. Tofeti ni wọn yóo sì máa sin òkú sí nígbà tí kò bá sí ààyè ní ibòmíràn mọ́. Òkú àwọn eniyan yìí yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati fún àwọn ẹranko, kò sì ní sí ẹni tí yóo lé wọn. N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní Jerusalẹmu, a kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé níbẹ̀ mọ́; nítorí pé n óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro.

Jer 7:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA. “Dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé OLúWA kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí: “ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin OLúWA. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni tẹmpili OLúWA ilé tẹmpili OLúWA, ilé tẹmpili OLúWA!” Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti iṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́. Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín. Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé. Ẹ wò ó, ẹ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́. “ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ ṣe panṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Baali, kí ẹ sì tọ ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ? Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” àwa yè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra wọ̀nyí bí? Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni OLúWA wí. “ ‘Ẹ lọ nísinsin yìí sí Ṣilo níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Israẹli tí í ṣe ènìyàn mi. Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni OLúWA wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí Ṣilo sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé tẹmpili nínú èyí tí ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ààyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín. Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Efraimu.’ “Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ. Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè. Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni OLúWA wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn? “ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èso orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa. “ ‘Èyí ni OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnrayín. Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán. Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé: Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn. Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Ejibiti títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín. Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’ “Nígbà tí ìwọ bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn. Nítorí náà, sọ fún wọn pé ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ti OLúWA Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn. “ ‘Gé irun yín kí ẹ sì dàánù, pohùnréré ẹkún lórí òkè, nítorí OLúWA ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀. “ ‘Àwọn ènìyàn Juda ti ṣe búburú lójú mi, ni OLúWA wí. Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́. Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tofeti ní Àfonífojì Beni-Hinnomu láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò pàṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi. Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni OLúWA wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí Àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ Àfonífojì Ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́ Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.