Jer 6:16-30

Jer 6:16-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bayi li Oluwa wi, ẹ duro li oju ọ̀na, ki ẹ si wò, ki ẹ si bere oju-ọ̀na igbàni, ewo li ọ̀na didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio rin. Pẹlupẹlu mo fi oluṣọ sọdọ nyin, ti o wipe, Ẹ fi eti si iro fère. Ṣugbọn nwọn wipe, awa kì yio feti si i. Nitorina, gbọ́, ẹnyin orilẹ-ède, ki ẹ si mọ̀, ẹnyin ijọ enia, ohun ti o wà ninu wọn! Gbọ́, iwọ ilẹ! wò o, emi o mu ibi wá si ori enia yi, ani eso iro inu wọn, nitori nwọn kò fi eti si ọ̀rọ mi, ati ofin mi ni nwọn kọ̀ silẹ. Ère wo li o wà fun mi ninu turari lati Ṣeba wá, ati ẽsu daradara lati ilẹ ti o jina wá? ọrẹ sisun nyin kò ṣe inu-didun mi, ẹbọ jijẹ nyin kò wù mi. Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ohun idugbolu siwaju awọn enia yi, ti baba ati awọn ọmọ yio jumọ ṣubu lù wọn, aladugbo ati ọrẹ rẹ̀ yio ṣegbe. Bayi li Oluwa wi, sa wò o, enia kan ti ilu ariwa wá, ati orilẹ-ède nla kan yio ti opin ilẹ aiye dide wá. Nwọn di ọrun ati ọ̀kọ mu; onroro ni nwọn, nwọn kò ni ãnu; ohùn wọn yio hó bi okun; nwọn gun ẹṣin; nwọn si mura bi ọkunrin ti yio ja ọ logun, iwọ ọmọbinrin Sioni. Awa ti gbọ́ òkiki eyi na: ọwọ wa di rirọ, ẹ̀dun ti di wa mu, ati irora bi obinrin ti nrọbi. Máṣe lọ si inu oko, bẹ̃ni ki o má si rin oju ọ̀na na, nitori idà ọ̀ta, idagiri wà yikakiri. Iwọ, ọmọbinrin enia mi, di ara rẹ ni amure aṣọ-ọ̀fọ ki o si ku ẽru sara, ṣe ọ̀fọ bi ẹniti nṣọ̀fọ fun ọmọ rẹ̀ nikanṣoṣo, pohùnrere kikoro: nitori afiniṣe-ijẹ yio ṣubu lù wa lojiji. Emi ti fi ọ ṣe ẹniti o ma dán ni wò, odi alagbara lãrin enia mi, ki iwọ ki o le mọ̀ ki o si le dan ọ̀na wọn wò. Gbogbo nwọn ni alagidi ọlọtẹ̀, ti nrin kiri sọ̀rọ̀ ẹni lẹhin, idẹ ati irin ni nwọn; abanijẹ ni gbogbo nwọn iṣe. Ẹwìri joná, iná ti jẹ ojé, ẹniti nyọ ọ, nyọ ọ lasan, a kò si ya enia buburu kuro. Fàdaka bibajẹ ni enia yio ma pè wọn, nitori Oluwa ti kọ̀ wọn silẹ.

Jer 6:16-30 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré, ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́, níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́. Kí ẹ lè ní ìsinmi.” Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní, “A kò ní tọ ọ̀nà náà.” Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín. Mo wí fún wọn pé, “Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!” Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.” OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn. Gbọ́! Ìwọ ilẹ̀; n óo fa ibi lé àwọn eniyan wọnyi lórí, wọn óo jèrè èso ìwà burúkú wọn; nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti tàpá sí òfin mi. Kí ni anfaani turari, tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba, tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá? N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi. Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi, wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ; ati baba, àtọmọ wọn, àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́, gbogbo wọn ni yóo parun.” OLUWA ní, “Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá, orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé. Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀, ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú. Ìró wọn dàbí híhó omi òkun, bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀. Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun, wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!” A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ; ìdààmú dé bá wa, bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí. Ẹ má lọ sinu oko, ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà, nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́, ìdágìrì sì wà káàkiri. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú; ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo; kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín. Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò, o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò, o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn, kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n. Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn, wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn. Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin, àmúlùmálà ni gbogbo wọn. Lóòótọ́ à ń fi ẹwìrì fẹ́ iná, òjé sì ń yọ́ lórí iná; ṣugbọn alágbẹ̀dẹ ń yọ́ irin lásán ni, kò mú ìbàjẹ́ ara rẹ̀ kúrò. Ìdọ̀tí fadaka tí a kọ̀ tì ni wọ́n, nítorí pé OLUWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Jer 6:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò, ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́, ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’ Èmi yan olùṣọ́ fún un yín, mo sì wí pé: ‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’ ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’ Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè; kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn. Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, èso ìrò inú wọn, nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀. Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá, tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré? Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ọrẹ yín kò sì wù mí.” Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Àwọn baba àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n, àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.” Báyìí ni OLúWA wí: “Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá, a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde láti òpin ayé wá. Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀, wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú. Wọ́n ń hó bí omi Òkun, bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ; wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Sioni.” Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí obìnrin tí ń rọbí. Má ṣe jáde lọ sí orí pápá tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà, ìpayà sì wà níbi gbogbo. Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá. “Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́ irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí, kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò. Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́. Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan, kí ó lè yọ́ òjé, ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán; a kò si ya ènìyàn búburú kúrò. A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀, nítorí OLúWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”