Jer 6:1-9

Jer 6:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa, kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu, nítorí pé nǹkan burúkú ati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá. Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà, ṣugbọn n óo pa á run. Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú, wọn yóo pa àgọ́ yí i ká, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú. Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun; ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!” Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú! Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru; kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!” Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé: “Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀; kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í. Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà, nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀. Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga, bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu. Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀, àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà, n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ, bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè. Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka, bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.”

Jer 6:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu, Ẹ fọn fèrè ní Tekoa! Kí ẹ gbé ààmì sókè lórí Beti-Hakeremu! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára. Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́. Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.” “Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i. Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.” Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká. Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò, nítorí pé ó kún fún ìninilára. Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi. Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀ kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé.” Èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli ní tónítóní bí àjàrà; na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”