Jer 6:1-15

Jer 6:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸNYIN ọmọ Benjamini, ẹ ko ẹrù nyin salọ kuro li arin Jerusalemu, ẹ si fun fère ni Tekoa, ki ẹ si gbe àmi soke ni Bet-hakeremu, nitori ibi farahàn lati ariwa wá; ani iparun nlanla. Emi ti pa ọmọbinrin Sioni run, ti o ṣe ẹlẹgẹ ati ẹlẹwà. Awọn oluṣọ-agutan pẹlu agbo wọn yio tọ̀ ọ wá, nwọn o pa agọ wọn yi i ka olukuluku yio ma jẹ ni àgbegbe rẹ̀. Ẹ ya ara nyin si mimọ́ lati ba a jagun; dide, ki ẹ si jẹ ki a goke li ọsan. Egbe ni fun wa! nitori ọjọ nlọ, nitori ojiji ọjọ alẹ nà jade. Dide, ẹ jẹ ki a goke lọ li oru, ki a si pa ãfin rẹ̀ run. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ke igi lulẹ, ki ẹ si wà yàra ka Jerusalemu; eyi ni ilu nla ti a o bẹ̀wo; kìki ininilara li o wà lãrin rẹ̀. Bi isun ti itú omi rẹ̀ jade, bẹ̃ni o ntú ìwa-buburu rẹ̀ jade: ìwa-ipa ati ìka li a gbọ́ niwaju mi nigbagbogbo ninu rẹ̀, ani aisan ati ọgbẹ́. Gbọ́ ẹkọ́, Jerusalemu, ki ẹmi mi ki o má ba lọ kuro lọdọ rẹ; ki emi má ba sọ ọ di ahoro, ilẹ ti a kò gbe inu rẹ̀. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, jẹ ki nwọn ki o pẽṣẹ iyokù Israeli bi àjara: yi ọwọ rẹ pada bi aká-eso-ajara sinu agbọ̀n. Tani emi o sọ fun, ti emi o kilọ fun ti nwọn o si gbọ́? sa wò o, eti wọn jẹ alaikọla, nwọn kò si le fi iye si i: sa wò o, ọ̀rọ Oluwa di ẹ̀gan si wọn, nwọn kò ni inu didùn ninu rẹ̀. Nitorina emi kún fun ikannu Oluwa, ãrẹ̀ mu mi lati pa a mọra: tu u jade sori ọmọde ni ita, ati sori ajọ awọn ọmọkunrin pẹlu: nitori a o mu bãle pẹlu aya rẹ̀ ni igbekun, arugbo pẹlu ẹniti o ni ọjọ kikún lori. Ile wọn o di ti ẹlomiran, oko wọn ati aya wọn lakopọ̀: nitori emi o nà ọwọ mi si ori awọn olugbe ilẹ na, li Oluwa wi. Lati kekere wọn titi de nla wọn, gbogbo wọn li o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati woli titi de alufa, gbogbo wọn ni nṣe eke. Nwọn si ti wo ọgbẹ ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀; nwọn wipe, Alafia! Alafia! nigbati kò si alafia. A mu itiju ba wọn, nitoriti nwọn ṣe ohun irira: sibẹ nwọn kò tiju kan pẹlu, pẹlupẹlu õru itiju kò mu wọn: nitorina nwọn o ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu: nigbati emi ba bẹ̀ wọn wo, a o wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.

Jer 6:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa, kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu, nítorí pé nǹkan burúkú ati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá. Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà, ṣugbọn n óo pa á run. Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú, wọn yóo pa àgọ́ yí i ká, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú. Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun; ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!” Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú! Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru; kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!” Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé: “Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀; kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í. Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà, nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀. Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga, bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu. Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀, àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà, n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ, bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè. Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka, bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.” Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́? Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà? Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́. Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn, wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́. Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru, ara mi kò sì gbà á mọ́.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba, ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí. Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya, àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́. Ilé wọn yóo di ilé onílé, oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù; láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa, èké ni gbogbo wọn. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná, wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’, nígbà tí kò sí alaafia. Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì. Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú, a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jer 6:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu, Ẹ fọn fèrè ní Tekoa! Kí ẹ gbé ààmì sókè lórí Beti-Hakeremu! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára. Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́. Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.” “Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i. Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.” Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká. Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò, nítorí pé ó kún fún ìninilára. Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi. Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀ kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé.” Èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli ní tónítóní bí àjàrà; na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.” Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ OLúWA, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀. Èmi kún fún ìbínú OLúWA, èmi kò sì le è pa á mọ́ra. “Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí. Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni OLúWA wí. “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn. Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’ nígbà tí kò sì sí àlàáfíà. Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,” ni OLúWA wí.