Jer 49:7-22

Jer 49:7-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

Si Edomu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Kò ha si ọgbọ́n mọ ni Temani? a ha ke imọran kuro lọdọ oloye? ọgbọ́n wọn ha danu bi? Ẹ sa, ẹ yipada, ẹ ṣe ibi jijin lati ma gbe ẹnyin olugbe Dedani; nitori emi o mu wahala Esau wá sori rẹ̀, àkoko ti emi o bẹ̀ ẹ wò. Bi awọn aka-eso ba tọ̀ ọ wá, nwọn kì o ha kù ẽṣẹ́ eso ajara silẹ? bi awọn ole ba wá li oru, nwọn kì o ha parun titi yio fi tẹ́ wọn lọrùn. Nitori emi ti tú Esau ni ihoho, emi ti fi ibi ikọkọ rẹ̀ han, on kì o si le fi ara rẹ̀ pamọ; iru-ọmọ rẹ̀ di ijẹ, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn aladugbo rẹ̀, nwọn kò sí mọ́. Fi awọn ọmọ alainibaba rẹ silẹ, emi o si pa wọn mọ lãye; ati ki awọn opó rẹ ki o gbẹkẹle mi. Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, awọn ẹniti kò jẹbi, lati mu ninu ago, ni yio mu u lõtọ: iwọ o ha si lọ li alaijiya? iwọ kì yio lọ li alaijiya, nitori lõtọ iwọ o mu u. Nitori emi ti fi ara mi bura, li Oluwa wi pe: Bosra yio di ahoro, ẹ̀gan, idahoro, ati egún; ati gbogbo ilu rẹ̀ ni yio di ahoro lailai. Ni gbigbọ́ emi ti gbọ́ iró lati ọdọ Oluwa wá, a si ran ikọ̀ si awọn orilẹ-ède pe, ẹ kó ara nyin jọ, ẹ wá sori rẹ̀, ẹ si dide lati jagun. Nitori, wò o, emi o ṣe ọ ni ẹni-kekere lãrin awọn orilẹ-ède, ẹni-ẹgan lãrin awọn enia. Ibanilẹ̀ru rẹ ti tan ọ jẹ, igberaga ọkàn rẹ, nitori iwọ ngbe palapala okuta, ti o joko li ori oke, bi iwọ tilẹ kọ́ itẹ́ rẹ ga gẹgẹ bi idì, sibẹ emi o mu ọ sọkalẹ lati ibẹ wá, li Oluwa wi. Edomu yio si di ahoro: olukuluku ẹniti o ba rekọja rẹ̀, yio dãmu, yio si rẹrin si gbogbo ipọnju rẹ̀. Gẹgẹ bi ni ibiṣubu Sodomu ati Gomorra ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; ẹnikan kì yio gbe ibẹ mọ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀. Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi? Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa ti o ti gbà si Edomu; ati èro rẹ̀ ti o ti gba si awọn olugbe Temani pe, Lõtọ awọn ẹniti o kere julọ ninu agbo-ẹran yio wọ́ wọn kiri, lõtọ nwọn o sọ buka wọn di ahoro lori wọn. Ilẹ o mì nipa ariwo iṣubu wọn, ariwo! a gbọ́ ohùn igbe rẹ̀ li Okun-pupa. Wò o, yio goke wá yio si fò gẹgẹ bi idì, yio si nà iyẹ rẹ̀ sori Bosra: ati li ọjọ na ni ọkàn awọn alagbara ọkunrin Edomu yio dabi ọkàn obinrin ni irọbi.

Jer 49:7-22 Yoruba Bible (YCE)

Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa Edomu nìyí: Ó ní, “Ṣé kò sí ọgbọ́n ní Temani mọ́ ni? Àbí àwọn amòye kò ní ìmọ̀ràn lẹ́nu mọ́? Ṣé ọgbọ́n ti rá mọ́ wọn ninu ni? Ẹ̀yin ará Dedani, ẹ pada kíá, ẹ máa sálọ. Ẹ wọ inú ihò lọ, kí ẹ lọ máa gbébẹ̀! Nítorí pé ní ìgbà tí mo bá jẹ ìran Esau níyà, n óo mú kí ibi dé bá wọn. Bí àwọn tí ń kórè èso àjàrà bá bẹ̀rẹ̀ sí kórè, ṣebí wọn a máa fi èso díẹ̀ díẹ̀ sílẹ̀? Bí àwọn olè bá wọlé lóru, ṣebí ìba ohun tí ó bá wù wọ́n ni wọn yóo kó? Ṣugbọn mo ti tú àwọn ọmọ Esau sí ìhòòhò, Mo ti sọ ibi tí wọn ń sápamọ́ sí di gbangba, wọn kò sì rí ibi sápamọ́ sí mọ́. Àwọn ọmọ wọn ti parun, pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn aládùúgbò wọn; àwọn pàápàá sì ti di àwátì. Fi àwọn ọmọ rẹ, aláìníbaba sílẹ̀, n óo pa wọ́n mọ́ láàyè, sì jẹ́ kí àwọn opó rẹ gbẹ́kẹ̀lé mi. “Bí àwọn tí kò yẹ kí wọ́n jìyà bá jìyà, ṣé ìwọ wá lè lọ láìjìyà? O kò ní lọ láìjìyà, dájúdájú ìyà óo jẹ ọ́. Nítorí pé mo ti fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, pé Bosira yóo di àríbẹ̀rù ati ohun ẹ̀gàn, ahoro ati ohun àmúgégùn-ún; àwọn ìlú rẹ̀ yóo sì di ahoro títí lae.” Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA, wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n ní kí wọn kéde pé, “OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu, ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í! Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeré láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, o óo sì di yẹpẹrẹ, láàrin àwọn ọmọ eniyan. Ẹ̀rù tí ó wà lára rẹ, ati ìgbéraga ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ò ń gbé pàlàpálá àpáta, tí o fi góńgó orí òkè ṣe ibùgbé. Bí o tilẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga, bíi ti ẹyẹ idì, n óo fà ọ́ lulẹ̀ láti ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA ní, “Edomu yóo sì di ibi àríbẹ̀rù, ẹ̀rù yóo máa ba gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba ibẹ̀ kọjá, wọn yóo máa pòṣé nítorí ibi tí ó dé bá a. Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí? Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn. Ariwo wíwó odi Edomu wọn yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ títí dé etí òkun pupa. Wò ó! Ẹnìkan yóo fò bí ẹyẹ idì, yóo na ìyẹ́ rẹ̀ sórí Bosira, ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ọmọ ogun Edomu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ń rọbí.”

Jer 49:7-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nípa Edomu: Èyí ní ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí? Yípadà kí o sálọ, sápamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani, nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau, ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò. Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá; ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀? Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́? Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò, èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn, nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́. Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun. Wọn kò sì ní sí mọ́. Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un. Èmi fi ara mi búra ni OLúWA wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.” Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ OLúWA: A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé, Ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun. “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo; ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn. Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni OLúWA wí. “Edomu yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní OLúWA wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́. “Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?” Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLúWA ní fún Edomu, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde. Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn. Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn, a ó gbọ́ igbe wọn ní Òkun pupa. Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀, yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.