Jer 47:1-2
Jer 47:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah woli wá, si awọn ara Filistia, ki Farao ki o to kọlu Gasa. Bayi li Oluwa wi; Wò o, omi dide lati ariwa, yio si jẹ kikun omi akunya, yio si ya bo ilẹ na, ati gbogbo ẹkún inu rẹ̀; ilu na, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀: nigbana ni awọn enia yio kigbe, gbogbo awọn olugbe ilẹ na yio si hu.
Jer 47:1-2 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa, Ó ní, “Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá, yóo di àgbàrá tí ó lágbára; yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀, yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
Jer 47:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ọ̀rọ̀ OLúWA tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa: Báyìí ni OLúWA wí: “Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá, wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀. Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀, ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn. Àwọn ènìyàn yóò kígbe; gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu