Jer 44:16-17
Jer 44:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀rọ ti iwọ sọ fun wa li orukọ Oluwa, awa kì yio feti si tirẹ. Ṣugbọn dajudaju awa o ṣe ohunkohun ti o jade lati ẹnu wa wá, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, gẹgẹ bi awa ti ṣe, awa, ati awọn baba wa, awọn ọba wa, ati awọn ijoye wa ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nigbana awa ni onjẹ pupọ, a si ṣe rere, a kò si ri ibi.
Jer 44:16-17 Yoruba Bible (YCE)
wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA. Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi.
Jer 44:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Wọn sì wí pé: Àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ OLúWA. Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà naà àwa ní oúnjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi