Jer 40:2-3
Jer 40:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Balogun iṣọ si mu Jeremiah, o si wi fun u pe, Oluwa, Ọlọrun rẹ, ti sọ ibi yi si ilu yi. Oluwa si ti mu u wá, o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi: nitoripe ẹnyin ti ṣẹ̀ si Oluwa, ẹ kò si gbọ́ ohùn rẹ̀, nitorina ni nkan yi ṣe de ba nyin.
Pín
Kà Jer 40Jer 40:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, sọ fún Jeremaya pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ti pinnu láti ṣe ilẹ̀ yìí ní ibi; Ó sì ti ṣe bí ó ti pinnu nítorí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí i, ẹ kò sì fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí náà ni ibi ṣe dé ba yín.
Pín
Kà Jer 40Jer 40:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremiah, ó sọ fún un wí pé, “OLúWA Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi. Nísinsin yìí, OLúWA ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí OLúWA, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀.
Pín
Kà Jer 40