Jer 4:5-18
Jer 4:5-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ kede ni Juda, ki ẹ si pokikí ni Jerusalemu; ki ẹ si wipe, ẹ fun fère ni ilẹ na, ẹ ké, ẹ kojọ pọ̀, ki ẹ si wipe; Pè apejọ ara nyin, ki ẹ si lọ si ilu olodi wọnnì. Ẹ gbé ọpagun soke siha Sioni; ẹ kuro, ẹ má duro: nitori emi o mu buburu lati ariwa wá pẹlu ibajẹ nlanla. Kiniun jade wá lati inu pantiri rẹ̀, ati olubajẹ awọn orilẹ-ède dide: o jade kuro ninu ipo rẹ̀ lati sọ ilẹ rẹ di ahoro; ati ilu rẹ di ofo, laini olugbe. Nitori eyi, di amure aṣọ ọ̀fọ, pohùnrere ki o si sọkun: nitori ibinu gbigbona Oluwa kò lọ kuro lọdọ wa. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ọkàn ọba yio nù, ati ọkàn awọn ijoye: awọn alufa yio si dãmu, hà yio si ṣe awọn woli. Nigbana ni mo wipe, Ye! Oluwa Ọlọrun! nitõtọ iwọ ti tan awọn enia yi ati Jerusalemu jẹ gidigidi, wipe, Ẹnyin o ni alafia; nigbati idà wọ inu ọkàn lọ. Nigbana ni a o wi fun awọn enia yi ati fun Jerusalemu pe, Ẹfũfu gbigbona lati ibi giga ni iju niha ọmọbinrin enia mi, kì iṣe lati fẹ, tabi lati fẹnù. Ẹfũfu ti o lagbara jù wọnyi lọ yio fẹ fun mi: nisisiyi emi pẹlu yio sọ̀rọ idajọ si wọn. Sa wò o, on o dide bi awọsanma, kẹ̀kẹ rẹ̀ yio dabi ìji: ẹṣin rẹ̀ yara jù idì lọ. Egbe ni fun wa! nitori awa di ijẹ. Jerusalemu! wẹ ọkàn rẹ kuro ninu buburu, ki a ba le gba ọ là. Yio ti pẹ to ti iro asan yio wọ̀ si inu rẹ. Nitori ohùn kan kede lati Dani wá, o si pokiki ipọnju lati oke Efraimu. Ẹ wi fun awọn orilẹ-ède; sa wò o, kede si Jerusalemu, pe, awọn ọluṣọ-ogun ti ilẹ jijin wá, nwọn si sọ ohùn wọn jade si ilu Juda. Bi awọn ti nṣọ oko, bẹ̃ni nwọn wà yi i kakiri: nitori o ti ṣọtẹ̀ si mi, li Oluwa wi. Ìwa rẹ ati iṣe rẹ li o ti mu gbogbo ohun wọnyi bá ọ; eyi ni buburu rẹ, nitoriti o korò, nitoriti o de ọkàn rẹ.
Jer 4:5-18 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ sọ ọ́ ní Juda, ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé, “Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà, kí ẹ sì kígbe sókè pé, ‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’ Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni, pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró, nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá. Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà; ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra; ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀, láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro. Yóo pa àwọn ìlú yín run, kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́. Nítorí èyí, ẹ fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ẹ sọkún kí ẹ máa ké tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí ìrúnú gbígbóná OLUWA kò tíì yipada kúrò lọ́dọ̀ wa.” OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.” Mo bá dáhùn pé, “Háà, OLUWA Ọlọrun, àṣé ò ń tan àwọn eniyan wọnyi, ati àwọn ará Jerusalẹmu ni, nígbà tí o sọ fún wọn pé, yóo dára fún wọn; àṣé idà ti dé ọrùn wọn!” A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù. Ìjì tí yóo ti ọ̀dọ̀ mi wá yóo le jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nisinsinyii èmi ni mò ń fi ọ̀rọ̀ mi dá wọn lẹ́jọ́. Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì. Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ. A gbé, nítorí ìparun dé bá wa. Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ, kí á lè gbà ọ́ là. Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ? Nítorí a gbọ́ ohùn kan láti ilẹ̀ Dani, tí ń kéde ibi láti òkè Efuraimu. Ẹ kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé ó ń bọ̀, kéde fún Jerusalẹmu pé, àwọn ológun tí ń dó ti ìlú ń bọ̀, láti ilẹ̀ òkèèrè. Wọ́n ń kọ lálá sí àwọn ìlú Juda. Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko, nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ìrìn ẹsẹ̀ rẹ ati ìwà rẹ ni ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá ọ. Ìjìyà rẹ nìyí, ó sì korò; ó ti dé oókan àyà rẹ.
Jer 4:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Kéde ní Juda, kí o sì polongo ní Jerusalẹmu, kí o sì wí pé: ‘Fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀!’ Kí o sì kígbe: ‘Kó ara jọ pọ̀! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’ Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn, sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró. Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá, àní ìparun tí ó burú jọjọ.” Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀, apanirun orílẹ̀-èdè sì ti jáde. Ó ti fi ààyè rẹ̀ sílẹ̀ láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́. Ìlú rẹ yóò di ahoro láìsí olùgbé. Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀ káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún, nítorí ìbínú ńlá OLúWA kò tí ì kúrò lórí wa. “Ní ọjọ́ náà,” ni OLúWA wí pé, “Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn, àwọn àlùfáà yóò wárìrì, àwọn wòlíì yóò sì fòyà.” Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.” Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́. Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.” Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ. Ègbé ni fún wa àwa parun. Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ? Ohùn kan sì ń kéde ní Dani o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá. “Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè, kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé: ‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda. Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá, nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ” ni OLúWA wí. “Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ ló fa èyí bá ọ ìjìyà rẹ sì nìyìí. Báwo ló ti ṣe korò tó! Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”