Jer 4:22 - Compare All Versions
Jer 4:22 YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori òpe li enia mi, nwọn kò mọ̀ mi; alaimoye ọmọ ni nwọn iṣe, nwọn kò si ni ìmọ: nwọn ni ọgbọ́n lati ṣe ibi, ṣugbọn oye ati ṣe rere ni nwọn kò ni.
Pín
Jer 4 YBCVJer 4:22 YCE (Yoruba Bible)
OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀, wọn kò mọ̀ mí. Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n; wọn kò ní òye. Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn: ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.”
Pín
Jer 4 YCEJer 4:22 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi; wọn kò mọ̀ mí. Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ; wọ́n sì jẹ́ aláìlóye. Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe; wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”
Pín
Jer 4 BMYO