Jer 4:19-31
Jer 4:19-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Inu mi, inu mi! ẹ̀dun dùn mi jalẹ de ọkàn mi; ọkàn mi npariwo ninu mi; emi kò le dakẹ, Nitoriti iwọ, ọkàn mi, ngbọ́ iro fère, ati idagiri ogun. Iparun lori iparun ni a nke; nitori gbogbo ilẹ li o ti parun, lojiji ni agọ mi di ijẹ, pẹlu aṣọ ikele mi ni iṣẹju kan. Yio ti pẹ to ti emi o ri ọpagun, ti emi o si gbọ́ iro fère? Nitori òpe li enia mi, nwọn kò mọ̀ mi; alaimoye ọmọ ni nwọn iṣe, nwọn kò si ni ìmọ: nwọn ni ọgbọ́n lati ṣe ibi, ṣugbọn oye ati ṣe rere ni nwọn kò ni. Mo bojuwo aiye, sa wò o, o wà ni jũju, o si ṣofo; ati ọrun, imọlẹ kò si lara rẹ̀. Mo bojuwo gbogbo oke nla, sa wò o, o warìri ati gbogbo oke kekere mì jẹjẹ. Mo bojuwo, sa wò o, kò si enia kan, pẹlupẹlu gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun sa lọ. Mo bojuwo, sa wò o, Karmeli di aginju, ati gbogbo ilu rẹ̀ li o wó lulẹ, niwaju Oluwa ati niwaju ibinu rẹ̀ gbigbona. Nitori bayi li Oluwa wi pe: Gbogbo ilẹ ni yio di ahoro; ṣugbọn emi kì yio ṣe ipari tan. Nitori eyi ni ilẹ yio ṣe kãnu, ati ọrun loke yio di dudu: nitori emi ti wi i, mo ti pete rẹ̀, emi kì o yi ọkàn da, bẹ̃ni kì o yipada kuro ninu rẹ̀. Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn. Ati iwọ, ẹniti o di ijẹ tan, kini iwọ o ṣe? Iwọ iba wọ ara rẹ ni aṣọ òdodó, iwọ iba fi wura ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ iba fi tirõ kun oju rẹ: lasan ni iwọ o ṣe ara rẹ daradara, awọn ayanfẹ rẹ yio kọ̀ ọ silẹ, nwọn o wá ẹmi rẹ. Nitori mo ti gbọ́ ohùn kan bi ti obinrin ti nrọbi, irora bi obinrin ti nbi akọbi ọmọ rẹ̀, ohùn ọmọbinrin Sioni ti npohùnrere ẹkun ara rẹ̀, ti o nnà ọwọ rẹ̀ wipe: Egbé ni fun mi nisisiyi nitori ãrẹ mu mi li ọkàn, nitori awọn apania.
Jer 4:19-31 Yoruba Bible (YCE)
Oró ò! Oró ò! Mò ń jẹ̀rora! Àyà mi ò! Àyà mi ń lù kìkìkì, n kò sì lè dákẹ́; nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun. Àjálù ń ṣubú lu àjálù, gbogbo ilẹ̀ ti parun. Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀, aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan. Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun, tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun? OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀, wọn kò mọ̀ mí. Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n; wọn kò ní òye. Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn: ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.” Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo, ó rí júujùu; mo ṣíjú wo ojú ọ̀run, kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀. Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì, gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún. Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan, gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ. Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀, gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA, nítorí ibinu ńlá rẹ̀. Nítorí OLUWA ti sọ pé, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro; sibẹ òpin kò ní tíì dé. Nítorí èyí, ilẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀, ojú ọ̀run yóo sì ṣókùnkùn. Nítorí pé ó ti sọ bẹ́ẹ̀, ó ti rò ó dáradára, kò tíì jáwọ́ ninu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní yipada. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin ati ti àwọn tafàtafà, gbogbo ìlú sá jáde fún ààbò. Wọ́n sá wọ inú igbó lọ, wọ́n gun orí òkè lọ sinu pàlàpálá òkúta; gbogbo ìlú sì di ahoro. Ìwọ tí o ti di ahoro, kí ni èrò rẹ tí o fi wọ aṣọ elése àlùkò? Tí o wa nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà sára? Tí o tọ́ ojú? Tí o tọ́ ètè? Asán ni gbogbo ọ̀ṣọ́ tí o ṣe, àwọn olólùfẹ́ rẹ kò kà ọ́ sí, ọ̀nà ati gba ẹ̀mí rẹ ni wọ́n ń wá. Nítorí mo gbọ́ igbe kan, tí ó dàbí igbe obinrin tí ó ń rọbí, ó ń kérora bí aboyún tí ó ń rọbí alákọ̀ọ́bí. Mo gbọ́ igbe Jerusalẹmu tí ń pọ̀ọ̀kà ikú, tí ó na ọwọ́ rẹ̀ síta, tí ń ké pé, “Mo gbé! Mò ń kú lọ, lọ́wọ́ àwọn apànìyàn!”
Jer 4:19-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Háà! Ìrora mi, ìrora mi! Mo yí nínú ìrora. Háà, ìrora ọkàn mi! Ọkàn mi lù kìkì nínú mi, n kò le è dákẹ́. Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè, mo sì ti gbọ́ igbe ogun. Ìparun ń gorí ìparun; gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi, tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan. Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè? “Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi; wọn kò mọ̀ mí. Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ; wọ́n sì jẹ́ aláìlóye. Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe; wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.” Mo bojú wo ayé, ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo àti ní ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì ṣí. Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n wárìrì; gbogbo òkè kéékèèké mì jẹ̀jẹ̀. Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan; gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ. Mo bojú wò, ilẹ̀ eléso, ó sì di aṣálẹ̀ gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparun níwájú OLúWA àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀. Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro, síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátápátá. Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀ mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.” Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà gbogbo ìlú yóò sálọ. Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó; ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ. Gbogbo ìlú náà sì di ahoro; kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀. Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán? Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ; wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ. Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí, tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ ọmọbìnrin Sioni tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀. Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé, “Kíyèsi i mo gbé, nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”