Jer 36:20-26
Jer 36:20-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si wọle tọ̀ ọba lọ ninu àgbala, ṣugbọn nwọn fi iwe-kiká na pamọ si iyara Eliṣama, akọwe, nwọn si sọ gbogbo ọ̀rọ na li eti ọba. Ọba si rán Jehudu lati lọ mu iwe-kiká na wá: on si mu u jade lati inu iyara Eliṣama, akọwe. Jehudu si kà a li eti ọba, ati li eti gbogbo awọn ijoye, ti o duro tì ọba. Ọba si ngbe ile igba-otutu li oṣu kẹsan: ina si njo niwaju rẹ̀ ninu idana. O si ṣe, nigbati Jehudu ti kà ewe mẹta tabi mẹrin, ọba fi ọbẹ ke iwe na, o si sọ ọ sinu iná ti o wà ninu idaná, titi gbogbo iwe-kiká na fi joná ninu iná ti o wà lori idaná. Sibẹ nwọn kò warìri, nwọn kò si fa aṣọ wọn ya, ani ọba, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti o gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi. Ṣugbọn Elnatani ati Delaiah ati Gemariah bẹbẹ lọdọ ọba ki o máṣe fi iwe-kiká na joná, kò si fẹ igbọ́ ti wọn. Ṣugbọn ọba paṣẹ fun Jerameeli, ọmọ Hameleki, ati Seraiah, ọmọ Asraeli, ati Ṣelemiah, ọmọ Abdeeli, lati mu Baruku akọwe, ati Jeremiah woli: ṣugbọn Oluwa fi wọn pamọ.
Jer 36:20-26 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un. Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ninu oṣù kẹsan-an ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ọba sì wà ní ilé tíí máa gbé ní àkókò òtútù, iná kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ń jó ninu agbada. Bí Jehudi bá ti ka òpó mẹta tabi mẹrin ninu ìwé náà, ọba yóo fi ọ̀bẹ gé e kúrò, yóo sì jù ú sinu iná tí ń jó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe títí ó fi fi ìwé náà jóná tán. Sibẹ ẹ̀rù kò ba ọba tabi àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò sì fa aṣọ wọn ya. Elinatani, Dilaaya ati Gemaraya tilẹ̀ bẹ ọba pé kí ó má fi ìwé náà jóná, ṣugbọn kò gbà. Ọba bá pàṣẹ fún Jerameeli ọmọ rẹ̀, ati Seraaya ọmọ Asirieli, ati Ṣelemaya ọmọ Abideeli, pé kí wọn lọ mú Baruku akọ̀wé, ati Jeremaya wolii wá, ṣugbọn OLUWA fi wọ́n pamọ́.
Jer 36:20-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíká náà pamọ́ sí iyàrá Eliṣama akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí ọba. Ọba sì rán Jehudu láti lọ mú ìwé kíká náà wá, Jehudu sì mu jáde láti inú iyàrá Eliṣama akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti ọba. Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsànán, ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná ààrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀. Nígbà tí Jehudu ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé kíká náà fi jóná tán. Síbẹ̀, ọba àti gbogbo àwọn ẹ̀mẹwàá rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá. Elnatani, Delaiah àti Gemariah sì bẹ ọba kí ó má ṣe fi ìwé kíká náà jóná, ṣùgbọ́n ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn. Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi wọ́n pamọ́.