Jer 31:27-40
Jer 31:27-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbin ile Israeli ati Judah ni irugbin enia, ati irugbin ẹran. Yio si ṣe, pe gẹgẹ bi emi ti ṣọ́ wọn, lati fà tu, ati lati fa lulẹ, ati lati wo lulẹ, ati lati parun, ati lati pọnloju, bẹ̃ni emi o ṣọ́ wọn, lati kọ́, ati lati gbìn, li Oluwa wi. Li ọjọ wọnni, nwọn kì yio wi mọ pe, Awọn baba ti jẹ eso ajara aipọn, ehín si ti kan awọn ọmọ. Ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori aiṣedede rẹ̀, olukuluku ti o jẹ eso ajara-aipọn ni ehín yio kan. Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o ba ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun. Kì iṣe bi majẹmu na ti emi ba baba wọn dá li ọjọ na ti emi fà wọn lọwọ lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti: awọn ti nwọn dà majẹmu mi, bi emi tilẹ jẹ alakoso wọn sibẹ, li Oluwa wi; Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi. Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rẹ̀, ati ẹ̀gbọn, aburo rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ̀ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li Oluwa wi; nitori emi o dari aiṣedede wọn ji, emi kì o si ranti ẹ̀ṣẹ wọn mọ. Bayi li Oluwa wi ti o fi õrùn fun imọlẹ li ọsan, ilana oṣupa ati irawọ fun imọlẹ li oru, ti o rú okun soke tobẹ̃, ti riru omi rẹ̀ nho; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: Bi ilana wọnyi ba yẹ̀ kuro niwaju mi, li Oluwa wi, njẹ iru-ọmọ Israeli pẹlu yio dẹkun lati ma jẹ orilẹ-ède niwaju mi lailai. Bayi li Oluwa wi, Bi a ba le wọ̀n ọrun loke, ti a si le wá ipilẹ aiye ri nisalẹ, emi pẹlu yio ta iru-ọmọ Israeli nù nitori gbogbo eyiti nwọn ti ṣe, li Oluwa wi. Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti a o kọ́ ilu na fun Oluwa lati ile-iṣọ Hananeeli de ẹnu-bode igun odi. Okùn ìwọn yio si nà jade siwaju lẹba rẹ̀ lori oke Garebi, yio si lọ yi Goati ka. Ati gbogbo afonifoji okú, ati ti ẽru, ati gbogbo oko titi de odò Kidroni, titi de igun ẹnubode-ẹṣin niha ilà-õrun, ni yio jẹ mimọ́ fun Oluwa; a kì yio fà a tu, bẹ̃ni a kì yio si wó o lulẹ mọ lailai.
Jer 31:27-40 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo kó àtènìyàn, àtẹranko kún ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Juda. Nígbà tí àkókò bá tó, gẹ́gẹ́ bí mo tí ń ṣọ́ wọn tí mo fi fà wọ́n tu, tí mo wó wọn lulẹ̀, tí mo bì wọ́n wó, tí mo pa wọ́n run, tí mo sì mú kí ibi ó bá wọn; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣọ́ wọn tí n óo fi kọ́ àwọn ìlú wọn tí n óo sì fìdí wọn múlẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Tó bá dìgbà náà, àwọn eniyan kò ní máa wí mọ́ pé, ‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà kíkan, àwọn ọmọ wọn ni eyín kan.’ Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó bá jẹ èso àjàrà kíkan, òun ni eyín yóo kan. Olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ń óo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn. Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi. Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán, tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́, tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya, òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun. Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun, ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae. Àfi bí eniyan bá lè wọn ojú ọ̀run, tí ó sì lè wádìí ìpìlẹ̀ ayé, ni òun lè ké àwọn ọmọ Israẹli kúrò, nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe. OLUWA ni, “Ẹ wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí a óo tún Jerusalẹmu kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli títí dé Bodè Igun. A óo ta okùn ìwọ̀n odi ìlú títí dé òkè Garebu, ati títí dé Goa pẹlu. Gbogbo àfonífojì tí wọn ń da òkú ati eérú sí, ati gbogbo pápá títí dé odò Kidironi, dé ìkangun Bodè Ẹṣin, ní ìhà ìlà oòrùn, ni yóo jẹ́ ibi mímọ́ fún OLUWA. Wọn kò ní fọ́ ọ mọ́, ẹnìkan kò sì ní wó o lulẹ̀ títí laelae.”
Jer 31:27-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLúWA wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni OLúWA wí. “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé: “ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́n àti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’ Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan. “Ìgbà kan ń bọ̀,” ni OLúWA wí, “tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun. Kò ní dàbí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́, tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi. Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,” ni OLúWA wí. “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni OLúWA wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ OLúWA wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi. Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ OLúWA,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,” ni OLúWA wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí: ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru; tí ó rú omi Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. “Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,” ni OLúWA wí. “Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀, ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,” ni OLúWA wí. “Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni OLúWA wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè. Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Garebu yóò sì lọ sí Goa. Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì Kidironi ní ìhà ìlà-oòrùn títí dé igun ẹnu ibodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí OLúWA. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”