Jer 31:1-26

Jer 31:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI àkoko na, li Oluwa wi, li emi o jẹ Ọlọrun gbogbo idile Israeli, nwọn o si jẹ enia mi. Bayi li Oluwa wi, Enia ti o sala lọwọ idà ri ore-ọfẹ li aginju, ani Israeli nigbati emi lọ lati mu u lọ si isimi rẹ̀. Oluwa ti fi ara hàn fun mi lati okere pe, Nitõtọ emi fi ifẹni aiyeraiye fẹ ọ, nitorina ni emi ti ṣe pa ore-ọfẹ mọ fun ọ. Emi o tun ọ kọ́, iwọ o si di kikọ, iwọ wundia Israeli! iwọ o si fi timbreli rẹ ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ o si jade lọ ni ọwọ́-ijo ti awọn ti nyọ̀. Iwọ o gbìn ọgba-ajara sori oke Samaria: awọn àgbẹ yio gbìn i, nwọn o si jẹ ẹ. Nitori ọjọ na ni eyi, ti awọn oluṣọ lori oke Efraimu yio kigbe pe, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a goke lọ si Sioni sọdọ Oluwa, Ọlọrun wa. Nitori bayi li Oluwa wi; ẹ fi ayọ̀ kọrin didùn fun Jakobu, ẹ si ho niti olori awọn orilẹ-ède: ẹ kede! ẹ yìn, ki ẹ si wipe: Oluwa, gbà awọn enia rẹ la, iyokù Israeli! Wò o, emi o mu wọn lati ilẹ ariwa wá, emi o si kó wọn jọ lati àgbegbe ilẹ aiye, afọju ati ayarọ pẹlu wọn, aboyun ati ẹniti nrọbi ṣọkan pọ̀: li ẹgbẹ nlanla ni nwọn o pada sibẹ. Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède, ẹ sọ ọ ninu erekuṣu òkere, ki ẹ si wipe, Ẹniti o tú Israeli ka yio kó o jọ, yio si pa a mọ, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo-ẹran rẹ̀. Nitori Oluwa ti tú Jakobu silẹ, o si rà a pada li ọwọ awọn ti o li agbara jù u lọ. Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara. Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn. Emi o si fi sisanra tẹ ọkàn awọn alufa lọrun, ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li Oluwa wi. Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si. Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta. Ireti si wà ni igbẹhin rẹ, li Oluwa wi, pe awọn ọmọ rẹ yio pada si agbegbe wọn. Lõtọ emi ti gbọ́ Efraimu npohùnrere ara rẹ̀ bayi pe; Iwọ ti nà mi, emi si di ninà, bi ọmọ-malu ti a kò kọ́; yi mi pada, emi o si yipada; nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun mi. Lõtọ lẹhin ti emi yipada, mo ronupiwada; ati lẹhin ti a kọ́ mi, mo lu ẹ̀gbẹ mi: oju tì mi, lõtọ, ani mo dãmu, nitoripe emi ru ẹ̀gan igba ewe mi. Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi. Gbe àmi-ọ̀na soke, ṣe ọwọ̀n àmi: gbe ọkàn rẹ si opopo ọ̀na, ani ọ̀na ti iwọ ti lọ: tun yipada, iwọ wundia Israeli, tun yipada si ilu rẹ wọnyi. Iwọ o ti ṣina kiri pẹ to, iwọ apẹhinda ọmọbinrin? nitori Oluwa dá ohun titun ni ilẹ na pe, Obinrin kan yio yi ọkunrin kan ka. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Nwọn o si tun lò ède yi ni ilẹ Juda ati ni ilu rẹ̀ wọnni, nigbati emi o mu igbekun wọn pada, pe, Ki Oluwa ki o bukun ọ, Ibugbe ododo, Oke ìwa-mimọ́! Juda ati gbogbo ilu rẹ̀ yio ma jumọ gbe inu rẹ̀, agbẹ, ati awọn ti mba agbo-ẹran lọ kakiri, Nitori emi tù ọkàn alãrẹ ninu, emi si ti tẹ gbogbo ọkàn ikãnu lọrun. Lori eyi ni mo ji, mo si wò; õrun mi si dùn mọ mi.

Jer 31:1-26 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli, tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀; nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi, OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè. Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ, nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò. N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú. Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria; àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀. Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni, sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ” OLUWA ní, “Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu, kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé, ‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ là àní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’ Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá, n óo kó wọn jọ láti òpin ayé. Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn, ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́. Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí. Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá, tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada. N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn, lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ; nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.” OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré; ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ, yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’ Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada, yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ. Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni, wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn: Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró, ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù; ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́. Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá. N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn. N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ, n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni. Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́. Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù, nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn. Ìrètí ń bẹ fún ọ lẹ́yìn ọ̀la, àwọn ọmọ rẹ yóo pada sí orílẹ̀-èdè wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Mo gbọ́ bí Efuraimu tí ń kẹ́dùn, ó ní: ‘O ti bá mi wí, ìbáwí sì dùn mí, bí ọmọ mààlúù tí a kò kọ́. Mú mi pada, kí n lè pada sí ààyè mi, nítorí pé ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun mi. Nítorí pé lẹ́yìn tí mo ṣáko lọ, mo ronupiwada; lẹ́yìn tí o kọ́ mi lọ́gbọ́n, ń ṣe ni mo káwọ́ lérí. Ojú tì mí, ìdààmú sì bá mi, nítorí ìtìjú ohun tí mo ṣe nígbà èwe mi dé bá mi.’ “Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni? Ṣé ọmọ mi àtàtà ni? Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀, nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí; dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀. Ẹ ri òpó mọ́lẹ̀ lọ fún ara yín, ẹ sàmì sí àwọn ojú ọ̀nà. Ẹ wo òpópónà dáradára, ẹ fiyèsí ọ̀nà tí ẹ gbà lọ. Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sí àwọn ìlú yín wọnyi. Ìgbà wo ni ẹ óo ṣe iyèméjì dà, ẹ̀yin alainigbagbọ wọnyi? Nítorí OLUWA ti dá ohun titun sórí ilẹ̀ ayé, bíi kí obinrin máa dáàbò bo ọkunrin.” OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóo tún máa lo gbolohun yìí ní ilẹ̀ Juda ati ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, wọn óo máa wí pé, ‘OLUWA yóo bukun ọ, ìwọ òkè mímọ́ Jerusalẹmu, ibùgbé olódodo.’ Àwọn eniyan yóo máa gbé àwọn ìlú Juda ati àwọn agbègbè rẹ̀ pẹlu àwọn àgbẹ̀ ati àwọn darandaran. Nítorí pé n óo fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní agbára; n óo sì tu gbogbo ọkàn tí ń kérora lára.” Lẹ́sẹ̀ kan náà mo tají, mo wò yíká, oorun tí mo sùn sì dùn mọ́ mi.

Jer 31:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

“Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni OLúWA wí. Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere OLúWA ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.” OLúWA ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín, Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀. Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà ní orí òkè Samaria; àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn. Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ OLúWA Ọlọ́run wa.’ ” Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLúWA sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘OLúWA, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’ Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá; èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé. Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ, aboyún àti obìnrin tí ń rọbí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá. Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún, wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà. Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi; ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú, nítorí èmi ni baba Israẹli, Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi. “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn; ‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’ Nítorí OLúWA ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padà ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ. Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni; wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore OLúWA. Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran. Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin, ìkorò kò ní bá wọn mọ́. Àwọn wúńdíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin. Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú. Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀. Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀; àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,” ni OLúWA wí. Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “A gbọ́ ohùn kan ní Rama tí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò. Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀; kò gbà kí wọ́n tu òun nínú, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.” Báyìí ni OLúWA wí: “Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún àti ojú rẹ nínú omijé; nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,” ni OLúWA wí. “Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá. Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,” ni OLúWA wí. “Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn. “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé, ‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́ èmi sì ti gbọ́ ìbáwí. Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà, nítorí ìwọ ni OLúWA Ọlọ́run mi. Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà, mo ronúpìwàdà, lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀, èmi lu àyà mi. Ojú tì mí, mo sì dààmú; nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’ Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí? Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀. Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un,” ni OLúWA wí. “Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde, ṣe atọ́nà àmì, kíyèsi òpópó ọ̀nà geere ojú ọ̀nà tí ó ń gbà. Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli, padà sí àwọn ìlú rẹ. Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin; OLúWA yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀, ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.” Báyìí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí OLúWA kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’ Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká. Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.” Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.