Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Jer 28:15-16

Jer 28:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni Jeremiah, woli, wi fun Hananiah, woli, pe, Gbọ́ nisisiyi, Hananiah; Oluwa kò rán ọ; ṣugbọn iwọ jẹ ki enia yi ki o gbẹkẹle eke. Nitorina bayi li Oluwa wi; Sa wo o, emi o ta ọ nù kuro loju aiye: li ọdun yi ni iwọ o kú, nitori iwọ ti sọ̀rọ iṣọtẹ si Oluwa.

Pín
Kà Jer 28

Jer 28:15-16 Yoruba Bible (YCE)

Jeremaya wolii bá sọ fún Hananaya pé, “Tẹ́tí sílẹ̀, Hananaya, OLUWA kò rán ọ níṣẹ́, o sì ń jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Nítorí náà, OLUWA ní: òun óo mú ọ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún yìí gan-an ni o óo sì kú, nítorí pé o ti sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”

Pín
Kà Jer 28

Jer 28:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wòlíì Jeremiah sọ fún wòlíì Hananiah pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! OLúWA kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́. Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí OLúWA.’ ”

Pín
Kà Jer 28
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò