Jer 26:1-11

Jer 26:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

NI ibẹrẹ ijọba Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ni ọ̀rọ yi ti ọdọ Oluwa wá wipe; Bayi li Oluwa wi, Duro ni àgbala ile Oluwa, ki o si sọ fun gbogbo ilu Juda ti o wá lati sìn ni ile Oluwa gbogbo ọ̀rọ ti mo pa laṣẹ fun ọ lati sọ fun wọn: máṣe ke ọ̀rọ kanṣoṣo kù: Bi o ba jẹ pe nwọn o gbọ́, ti olukuluku yio yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, ki emi ki o le yi ọkàn pada niti ibi ti emi rò lati ṣe si wọn, nitori iṣe buburu wọn. Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi: bi ẹnyin kì yio feti si mi lati rin ninu ofin mi, ti emi ti gbe kalẹ niwaju nyin. Lati gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, ti emi rán si nyin, ti mo ndide ni kutukutu, ti mo rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́. Emi o si ṣe ile yi bi Ṣilo, emi o si ṣe ilu yi ni ifibu si gbogbo orilẹ-ède aiye. Nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia gbọ́, bi Jeremiah ti nsọ ọ̀rọ wọnyi ni ile Oluwa. O si ṣe nigbati Jeremiah pari gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa paṣẹ fun u lati sọ fun gbogbo enia, nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia di i mu wipe, kikú ni iwọ o kú! Ẽṣe ti iwọ sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa wipe, Ile yi yio dabi Ṣilo, ati ilu yi yio di ahoro laini olugbe? Gbogbo enia kojọ pọ̀ tì Jeremiah ni ile Oluwa. Nigbati awọn ijoye Juda gbọ́ nkan wọnyi, nwọn jade lati ile ọba wá si ile Oluwa, nwọn si joko li ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa. Awọn alufa ati awọn woli wi fun awọn ijoye, ati gbogbo enia pe, ọkunrin yi jẹbi ikú nitoriti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, bi ẹnyin ti fi eti nyin gbọ́.

Jer 26:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Dúró sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA, kí o sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún gbogbo àwọn ará ìlú Juda tí wọn ń wá jọ́sìn níbẹ̀. Má fi ọ̀rọ̀ kankan pamọ́. Ó ṣeéṣe kí wọ́n gbọ́, kí olukuluku wọn sì yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀; kí n lè yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo fẹ́ ṣe sí wọn nítorí iṣẹ́ burúkú wọn. “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA ní bí wọn kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, kí wọn máa pa òfin tí mo gbé kalẹ̀ fún wọn mọ́, kí wọn sì máa gbọ́ràn sí àwọn iranṣẹ mi lẹ́nu, ati àwọn wolii mi tí mò ń rán sí wọn léraléra, bí wọn kò tilẹ̀ kà wọ́n sí, nítorí náà ni n óo ṣe ṣe ilé yìí bí mo ti ṣe Ṣilo; n óo sì sọ ìlú yìí di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóo máa fi gégùn-ún.” Àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan gbọ́ tí Jeremaya ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ilé OLUWA. Nígbà tí ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn eniyan náà tán, gbogbo wọn rá a mú, wọ́n ní, “Kíkú ni o óo kú! Kí ló dé tí o fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA pé ‘Ilé yìí yóo dàbí Ṣilo, ati pé ìlú yìí yóo di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbébẹ̀ mọ́?’ ” Gbogbo eniyan bá pé lé Jeremaya lórí ninu ilé OLUWA. Nígbà tí àwọn ìjòyè Juda gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lọ sí ilé OLUWA láti ààfin ọba, wọ́n sì jókòó ní Ẹnu Ọ̀nà Titun tí ó wà ní ilé OLUWA. Àwọn alufaa ati àwọn wolii bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “Ẹjọ́ ikú ni ó yẹ kí a dá fún ọkunrin yìí nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ń sọ nípa ìlú yìí, ẹ̀yin náà sá fi etí ara yín gbọ́.”

Jer 26:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba ọba Jehoiakimu ọmọ Josiah tí ń ṣe ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA: “Èyí ni ohun tí OLúWA wí, Dúró ní àgbàlá ilé OLúWA, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Juda tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé OLúWA, sọ fún gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà. Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n. Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín, àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́), nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ” Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé OLúWA. Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremiah ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí OLúWA pàṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dìímú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú! Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLúWA pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé OLúWA. Nígbà tí àwọn aláṣẹ Juda gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin ọba sí ilé OLúWA, wọ́n sì mú ààyè wọn, wọ́n jókòó ní ẹnu-ọ̀nà tuntun ilé OLúWA. Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”