Jer 25:1-14 - Compare All Versions

Jer 25:1-14 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli. Eyi ti Jeremiah, woli, sọ fun gbogbo enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe: Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i. Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́. Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai. Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi. Ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ temi, li Oluwa wi, ki ẹnyin le fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu si ibi ara nyin. Nitorina, bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitori ti ẹnyin kò gbọ́ ọ̀rọ mi. Sa wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu gbogbo idile orilẹ-ède ariwa wá, li Oluwa wi, emi o si ranṣẹ si Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi, emi o si mu wọn wá si ilẹ yi, ati olugbe rẹ̀, ati si gbogbo awọn orilẹ-ède yikakiri, emi o si pa wọn patapata, emi o si sọ wọn di iyanu ati iyọṣuti si, ati ahoro ainipẹkun. Pẹlupẹlu emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, iro okuta ọlọ, ati imọlẹ fitila kuro lọdọ wọn. Gbogbo ilẹ yi yio si di iparun ati ahoro: orilẹ-ède wọnyi yio si sìn ọba Babeli li ãdọrin ọdun. Yio si ṣe, nigbati ãdọrin ọdun ba pari tan, li emi o bẹ̀ ọba Babeli, ati orilẹ-ède na, ati ilẹ awọn ara Kaldea wò, nitori ẹ̀ṣẹ wọn; li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di ahoro titi lai. Emi o si mu gbogbo ọ̀rọ mi wá sori ilẹ na, ti mo ti sọ si i: ani gbogbo eyiti a ti kọ sinu iwe yi, eyiti Jeremiah ti sọtẹlẹ si gbogbo orilẹ-ède. Nitoriti awọn wọnyi pẹlu yio mu ki orilẹ-ède pupọ, ati awọn ọba nla sìn wọn: emi o san a fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn ati pẹlu gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn.

Jer 25:1-14 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli. Nítorí náà, Jeremiah wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti sí àwọn olùgbé Jerusalẹmu. Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLúWA ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí OLúWA fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé. Má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.” “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni OLúWA wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.” Nítorí náà, OLúWA àwọn ọmọ-ogun sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni OLúWA wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé. Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún. “Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé, Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Babeli àti orílẹ̀-èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Babeli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni OLúWA wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé. Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

Jer 25:1-14 YCE (Yoruba Bible)

Ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kinni tí Nebukadinesari jọba Babiloni, Jeremaya wolii gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nípa gbogbo àwọn ará Juda. Jeremaya sọ ọ̀rọ̀ náà fún gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu. Ó ní, “Fún ọdún mẹtalelogun, láti ọdún kẹtala tí Josaya ọmọ Amoni ti jọba Juda, títí di ọjọ́ òní, ni OLUWA ti ń bá mi sọ̀rọ̀, tí mo sì ti ń sọ ọ́ fun yín lemọ́lemọ́, ṣugbọn tí ẹ kò sì gbọ́. Ẹ kò fetí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo ni OLUWA ń rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, si yín, tí wọn ń sọ fun yín pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ ati iṣẹ́ ibi tí ó ń ṣe, kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí OLUWA fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín títí lae, láti ìgbà àtijọ́. Wọ́n ní kí ẹ má wá àwọn oriṣa lọ, kí ẹ má bọ wọ́n, kí ẹ má sì sìn wọ́n. Wọ́n ní kí ẹ má fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú un bínú, kí ó má baà ṣe yín ní ibi.” OLUWA alára ní, “Mo wí, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi; kí ẹ lè fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, fún ìpalára ara yín.” Ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àríwá wá. N óo ranṣẹ sí Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ mi, n óo jẹ́ kí wọn wá dó ti ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ yìí ni n óo parun patapata, tí n óo sọ di àríbẹ̀rù, ati àrípòṣé, ati ohun ẹ̀gàn títí lae. N óo pa ìró ayọ̀ ati ẹ̀rín rẹ́ láàrin wọn, ẹnìkan kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo tuntun mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí iná fìtílà mọ́. Gbogbo ilẹ̀ yìí yóo di àlàpà ati aṣálẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì sin ọba Babiloni fún aadọrin ọdún. Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, n óo jẹ ọba Babiloni ati orílẹ̀-èdè rẹ̀, ati ilẹ̀ àwọn ará Kalidea níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo sì sọ ibẹ̀ di àlàpà títí ayé. N óo mú gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú tí mo ti sọ nípa ilẹ̀ náà ṣẹ, ati gbogbo ohun tí a kọ sinu ìwé yìí, àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremaya sọ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba alágbára yóo sọ àwọn ará Babiloni pàápàá di ẹrú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san ìṣe wọn ati iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”