Jer 23:9-15

Jer 23:9-15 Yoruba Bible (YCE)

Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii, gbogbo ara mi ń gbọ̀n. Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó, mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa, nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀. Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àgbèrè ẹ̀sìn, ọ̀nà ibi ni wọ́n ń tọ̀, wọn kò sì lo agbára wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ nítorí ègún, ilẹ̀ ti di gbígbẹ gbogbo pápá oko ló ti gbẹ. Ati wolii, ati alufaa, ìwà burúkú ni wọ́n ń hù, ní ilé mi pàápàá mo rí iṣẹ́ ibi wọn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn, a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú, nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn. Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria: Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà. Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu: Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, wọ́n ń hùwà èké; wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀. Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi, àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora. Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé: N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ, n óo fún wọn ní omi májèlé mu. Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmu ni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí.

Jer 23:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Nípa ti àwọn wòlíì èké. Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi, gbogbo egungun mi ni ó wárìrì. Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn, bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa; nítorí OLúWA àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀. Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn; nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ, àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ. Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́. “Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run; kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,” ni OLúWA wí. “Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,” ni OLúWA wí. “Láàrín àwọn wòlíì Samaria, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá. Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà. Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu, èmi ti rí ohun búburú. Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké. Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀. Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.” Nítorí náà, báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”