Jer 18:4-6
Jer 18:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ. Ọrọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli.
Jer 18:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.
Jer 18:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá pé: “Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni OLúWA wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.