Jer 16:19-21
Jer 16:19-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, agbara mi ati ilu-odi mi! àbo mi li ọjọ ipọnju! awọn orilẹ-ède yio tọ̀ ọ wá, lati ipẹkun aiye, nwọn o si wipe, Lõtọ, awọn baba wa ti jogun eke, ohun asan, iranlọwọ kò si si ninu wọn! Enia lè ma dá ọlọrun fun ara rẹ̀: nitori awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun? Nitorina, sa wò o, emi o mu ki nwọn ki o mọ̀, lẹ̃kan yi, emi o si mu ki nwọn ki o mọ̀ ọwọ mi ati ipa mi; nwọn o si mọ̀ pe, orukọ mi ni JEHOFA.
Jer 16:19-21 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi, ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ, láti gbogbo òpin ayé, wọn yóo máa wí pé: “Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún, ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan. Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun? Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.” OLUWA ní, “Nítorí náà, wò ó, n óo jẹ́ kí wọn mọ̀; àní sẹ́, n óo jẹ́ kí wọ́n mọ agbára ati ipá mi; wọn yóo sì mọ̀ pé orúkọ mi ni OLUWA.”
Jer 16:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
OLúWA, alágbára àti okun mi, ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti òpin ayé wí pé, “Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà, ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.” “Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn ní àkókò yìí, Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú agbára àti títóbi mi. Nígbà náà ni wọn ó mọ pé orúkọ mi ní OLúWA.