Jer 14:7-11
Jer 14:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀. Iwọ, ireti Israeli, olugbala rẹ̀ ni wakati ipọnju! ẽṣe ti iwọ o dabi alejo ni ilẹ, ati bi èro ti o pa agọ lati sùn? Ẽṣe ti iwọ o dabi ẹniti o dãmu, bi ọkunrin akọni ti kò le ràn ni lọwọ? sibẹ iwọ, Oluwa, mbẹ li ãrin wa, a si npè orukọ rẹ mọ wa, má fi wa silẹ. Bayi li Oluwa wi fun awọn enia yi, bayi ni nwọn ti fẹ lati rò kiri, nwọn kò dá ẹsẹ wọn duro; Oluwa kò si ni inu-didun ninu wọn: yio ranti aiṣedẽde wọn nisisiyi, yio si bẹ ẹ̀ṣẹ wọn wò. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Máṣe gbadura fun awọn enia yi fun rere.
Jer 14:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa, sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá. Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ, a ti ṣẹ̀ ọ́. Ìwọ ìrètí Israẹli, olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro. Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà? Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú? Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá; bí alágbára tí kò lè gbani là? Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA, a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá, má fi wá sílẹ̀.’ ” OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé, “Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri, wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn; nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA, nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn, yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia.
Jer 14:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkan kan ṣe sí i OLúWA, nítorí orúkọ rẹ. Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ. Ìrètí Israẹli; ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú, èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré? Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú, bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́? Ìwọ wà láàrín wa, OLúWA, orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa; má ṣe fi wá sílẹ̀. Báyìí ni OLúWA sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà OLúWA kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí.